Apá Kẹwàá: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
Bá A Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Ní Iṣẹ́ Ìwàásù Ilé-dé-Ilé
1 Bí àwọn alàgbà bá pinnu pé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ti yẹ lẹ́ni tó lè di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, akẹ́kọ̀ọ́ náà lè bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ará lọ sóde ẹ̀rí. (Wo ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 79 sí 81.) Báwo la ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ kó lè dẹni tó ń wàásù láti ilé dé ilé?
2 Ẹ Jọ Máa Múra Sílẹ̀: Kò sóhun tá a lè fi rọ́pò ìmúrasílẹ̀ tó jíire. Kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà bó ṣe lè rí àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dábàá nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa àti nínú ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, kó o sì ràn án lọ́wọ́ láti yan ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó rọrùn tó sì bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu. Látìgbà tó o bá ti kọ́kọ́ mú un lọ sóde ẹ̀rí ni kó o ti gbà á nímọ̀ràn pé kó máa lo Bíbélì tó bá ń wàásù.—2 Tím. 4:2.
3 Àǹfààní tó pọ̀ ló wà nínú kí akéde tuntun máa ṣe ìdánrawò ṣáájú. Nígbà tí akéde náà bá ń ṣe ìdánrawò, kọ́ ọ bá a ṣe máa fọgbọ́n fèsì ọ̀rọ̀ táwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín sábà máa ń sọ. (Kól. 4:6) Fi í lọ́kàn balẹ̀ pé kì í ṣe dandan ni kí àwa tá à ń wàásù mọ ìdáhùn sí gbogbo ìbéèrè táwọn èèyàn bá bi wá. Ó sì tún máa ń dáa tá a bá sọ fún wọn pé a ó kọ́kọ́ lọ ṣèwádìí nílé tá a ó sì padà wá láti jíròrò ọ̀rọ̀ náà síwájú sí i.—Òwe 15:28.
4 Ẹ Jọ Máa Wàásù: Nígbà àkọ́kọ́ tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá tẹ̀lé ọ lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, ṣe ni kó o jẹ́ kó máa wo bó o ṣe ń lo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tẹ ẹ́ ti jọ múra sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, o lè wá ní kó dá sí i. Nígbà míì, ó lè jẹ́ pé ohun tó máa dáa jù ni pé kó o jẹ́ kí akéde tuntun náà ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀, kó sì ṣàlàyé rẹ̀. Fi ànímọ́ àti ìṣesí akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ́kàn o. (Fílí. 4:5) Má gbàgbé láti máa gbóríyìn fún un bó o ṣe ń kọ́ ọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé kóun náà lè di ẹni tó mọ iṣẹ́ ìwàásù ṣe dáadáa.
5 Ó ṣe pàtàkì pé kó o ran akéde tuntun lọ́wọ́ kóun náà lè mọ bó ṣe máa ṣètò táá fi lè máa jáde fún iṣẹ́ ìwàásù déédéé láìpa ọ̀sẹ̀ kankan jẹ, bó bá ṣeé ṣe. (Fílí. 3:16) Ẹ ṣètò pàtó kẹ́ ẹ lè jọ máa ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, kó o sì fún un níṣìírí pé kó máa bá àwọn mìíràn tó nítara ṣiṣẹ́. Àpẹẹrẹ àwọn tó ń bá jáde òde ẹ̀rí àti bí wọ́n ṣe jọ ń kẹ́gbẹ́ á jẹ́ kóun náà lè kúnjú ìwọ̀n, inú rẹ̀ á sì lè máa dùn bó ṣe ń wàásù láti ilé dé ilé.