Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 13
Orin 198
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù June sílẹ̀. Ẹ lo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ June 15 àti Jí! July 8. (Lo àbá kẹta fún Jí! July 8.) Ẹ tún lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà mìíràn tẹ́ ẹ bá fẹ́ lo ìwé ìròyìn náà. Nínú ọ̀kan lára ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà, ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo àwọn ìwé ìròyìn nígbà tá a ò bá sí lóde ẹ̀rí.
15 min: Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Di Akéde Tí Kò Tíì Ṣèrìbọmi. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí alàgbà kan yóò bójú tó látinú ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 79 sí 81. Jíròrò bá a ṣe máa ń pinnu bóyá akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ti kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ìwé Mímọ là kalẹ̀ láti lè máa bá ìjọ jáde òde ẹ̀rí. Lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, a óò jíròrò bá a ṣe lè kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n kúnjú ìwọ̀n láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé.
20 min: “Wíwàásù Ń Mú Ká Lè Lo Ìfaradà.”a Ní káwọn ará ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ bí àyè bá ṣe wà sí.
Orin 149 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 20
Orin 206
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti July 2003, ojú ìwé 8. Jẹ́ kí àwọn ará mọ bí wọ́n ṣe lè rí àwọn ìwé èdè ilẹ̀ òkèèrè gbà. Jíròrò bí ìsọfúnni yìí ṣe kan ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín. Ìwé èyíkéyìí lédè ilẹ̀ òkèèrè tẹ́ ẹ bá fẹ́ gbà, kódà kó jẹ́ ẹ̀dà kan ṣoṣo pàápàá, gbọ́dọ̀ jẹ́ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kẹ́ ẹ bàa lè rí ìwé náà gbà láìsí ìdádúró.
15 min: Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Sa Agbára. (Héb. 4:12) Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ November 15, 2003, ojú ìwé 11, ìpínrọ̀ 13 sí 17. Sọ àwọn ìrírí tó fi hàn pé àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Bíbélì lè mú kéèyàn yí ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ padà. (w00-YR 1/1 ojú ìwé 3 sí 5) Fún gbogbo àwọn ará ní ìṣírí láti máa lo Bíbélì bó ṣe yẹ nígbà tí wọ́n bá ń wàásù.
20 min: “Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú—Apá Kẹwàá.”b Ṣe àṣefihàn kan tó máa jẹ́ ìdánrawò bá a ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ṣe ń nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tán, olùkọ́ náà tó máa ṣe bí onílé á sọ nǹkan táwọn tí kì í fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín sábà máa ń sọ, bí akẹ́kọ̀ọ́ ò bá mọ ohun tó máa sọ mọ́, kí ìwọ tó ò ń darí apá yìí wá ṣàlàyé ọ̀nà tó máa gbé e gbà. Láfikún sí i, sọ fún akéde kan tàbí àwọn méjì kí wọ́n ti múra sílẹ̀ láti sọ ìtọ́ni tí wọ́n gbà kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí wàásù láti ilé dé ilé.
Orin 208 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 27
Orin 113
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn ará létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù June sílẹ̀. Lẹ́yìn ìròyìn ìnáwó, ka lẹ́tà tí ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́ nítorí ọrẹ tẹ́ ẹ fi ránṣẹ́. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu), láti fi lo Ilé Ìṣọ́ July 1 àti Jí! July 8 lóde ẹ̀rí. (Lo àbá kẹrin fún Jí! July 8.) Ẹ lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà mìíràn tẹ́ ẹ bá fẹ́ lo ìwé ìròyìn náà. Lẹ́yìn àṣefihàn, tún mẹ́nu ba ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí akẹ́kọ̀ọ́ náà lò láti lè mú kí onílé nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
20 min: Bá A Ṣe Lè Lo Àwọn Ìwé Pẹlẹbẹ Lóṣù July àti August. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka àkìbọnú. Ní ṣókí, ṣàlàyé bá a ṣe lè lo àkìbọnú náà, kó o sì fa kókó tó wà nínú àpótí tó wà ní ojú ìwé 3 yọ, àtèyí tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2005 lójú ìwé 8. Jíròrò àwọn àbá tó máa bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu bẹ́ ẹ bá ń lo ìwé pẹlẹbẹ fún ìgbà àkọ́kọ́. (Ẹ lè rí àwọn ọ̀nà tẹ́ ẹ lè gbà gbọ́rọ̀ kalẹ̀ síwájú sí i, bẹ́ ẹ bá fẹ́ lo ìwé Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I, nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 2003, ojú ìwé 8.) Ṣe àṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ méjì tàbí mẹ́ta. Jẹ́ kí ọmọdé kan tó jẹ́ akéde ṣe, ó kéré tán, ẹyọ kan lára àwọn àṣefihàn náà.
Orin 196 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 4
Orin 70
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
15 min: Ṣó O Ní Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdílé? Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn àbá tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù May 2005, kó o sì ní káwọn ará sọ ìsapá tí wọ́n ti ṣe láti lo àwọn àbá tó wà níbẹ̀ àti àǹfààní tí wọ́n ti rí gbà látinú títẹ̀ lé àwọn àbá náà.
20 min: “Wíwàásù Lọ́nà Tó Múná Dóko Níbi Térò Pọ̀ Sí.”c Darí rẹ̀ lọ́nà tó máa bá ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín mu. Rán àwọn ará létí pé kí wọn máa lo fọ́ọ̀mù Please Follow Up (S-43), bó bá yẹ.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 2005, ojú ìwé 6.
Orin 120 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.