Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bó O Ṣe Lè Dá Àwọn Ẹni Tuntun Lẹ́kọ̀ọ́
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbọ́dọ̀ kọ́ láti máa pa “gbogbo ohun tí” Jésù pa láṣẹ mọ́, tó ní nínú kíkọ́ àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (Mát. 28:19, 20) Ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun yìí ti tóótun láti ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ti lè máa jẹ́rìí láì-jẹ́-bí-àṣà fún àwọn aráalé wọn tàbí àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Àmọ́, bí ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ ṣe ń jinlẹ̀ lọ́kàn wọn, tí wọ́n sì mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ kí gbogbo èèyàn gbọ́ ìhìn rere, ó lè máa wù wọ́n láti kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. (Róòmù 10:13, 14) Tí àwọn ẹni tuntun bá ti di akéde tí kò tíì ṣe ìrìbọmi, ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó jíire tá a bá fún wọn á jẹ́ kí wọ́n lè túbọ̀ ní ìgboyà láti máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.—Lúùkù 6:40.
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Bá akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ ṣiṣẹ́ nígbà tẹ́ ẹ bá ń wàásù láti ilé-dé-ilé, kẹ́ ẹ sì jọ lọ sí ìpadàbẹ̀wò tàbí kẹ́ ẹ jọ lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ. Tí o kò bá ní ẹni tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o lè bá akéde kan tí kó fi bẹ́ẹ̀ nírìírí ṣiṣẹ́.