Bá A Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Ẹni Tuntun Láti Máa Wàásù
1. Báwo ló ṣe rí lára rẹ nígbà tó o kọ́kọ́ jáde òde ẹ̀rí?
1 Ǹjẹ́ o rántí ìgbà àkọ́kọ́ tó o wàásù láti ilé dé ilé? Ó ṣeé ṣe, kí àyà rẹ máa já gan-an nígbà yẹn. Bó bá jẹ́ pé ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí akéde míì lo bá ṣiṣẹ́, ó dájú pé inú rẹ dùn pé o rí ẹni ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ní báyìí tó o ti wá di òjíṣẹ́ tó nírìírí, ìwọ náà ti wá wà nípò láti kọ́ àwọn ẹni tuntun bí wọ́n ṣe máa wàásù.
2. Kí làwọn akéde tuntun ní láti kọ́?
2 Àwọn akéde tuntun ní láti kọ́ bí wọ́n ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú onílé, bí wọ́n ṣe máa lo Bíbélì lóde ẹ̀rí, bí wọ́n ṣe máa ṣe ìpadàbẹ̀wò kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n tún gbọ́dọ̀ kọ́ onírúurú ọ̀nà tí wọ́n lè gbà wàásù, irú bíi ìjẹ́rìí òpópónà àti wíwàásù ní àwọn ibi ìṣòwò. O lè ràn wọ́n lọ́wọ́ tó o bá ń fi bí wọ́n ṣe lè ṣe é hàn wọ́n, tó o sì ń fún wọn ní àwọn àbá tí wọ́n nílò.
3. Ọ̀nà wo la lè gbà jẹ́ àwòkọ́ṣe fún àwọn ẹlòmíì?
3 Jẹ́ Àwòkọ́ṣe: Jésù fi bá a ṣe ń wàásù han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Lúùkù 8:1; 1 Pét. 2:21) Bó o bá ṣètò láti bá akéde tuntun kan ṣiṣẹ́, lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tó máa rọrùn fún akéde náà láti lò, o lè lo ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà nínú ìtẹ̀jáde wa. Lẹ́yìn náà sọ fún un pé wàá wàásù ní ẹnu ọ̀nà kan tàbí méjì tẹ́ ẹ bá kọ́kọ́ dé kí akéde náà lè gbọ́ ohun tó o fẹ́ sọ. Tẹ́ ẹ bá ti kúrò lọ́dọ̀ onílé kan, o lè bi akéde náà nípa àkíyèsí tó ṣe lórí bí ìgbékalẹ̀ rẹ ṣe gbéṣẹ́ tó. Èyí máa jẹ́ kó rí àǹfààní tó wà nínú bíbá àwọn ẹlòmíì ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, á sì tún jẹ́ kó rọrùn fún un láti gba ìmọ̀ràn èyíkéyìí tó o bá fún un lẹ́yìn tóun náà bá ti bá ẹnì kan sọ̀rọ̀.
4. Báwo la ṣe lè ran akéde tuntun kan lọ́wọ́ lẹ́yìn tá a bá ti fetí sí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀?
4 Sọ Ohun Tí Wọ́n Lè Ṣe: Jésù tún fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni nípa bí wọ́n á ṣe máa wàásù. (Mát. 10:5-14) O lè ran akéde tuntun lọ́wọ́ lọ́nà kan náà. Tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá wá kúrò lọ́dọ̀ onílé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kó o rí àwọn ohun tó nílò àtúnṣe nínú bó ṣe gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀, jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti kọ́kọ́ máa gbóríyìn fún un nípa mímẹ́nu kan àwọn nǹkan pàtó tó o rí i pé ó ṣe dáadáa. Kó o tó sọ àwọn ohun tó ó fẹ́ kó ṣiṣẹ́ lé lórí, o lè kọ́kọ́ wò ó bóyá ó ti ṣiṣẹ́ lórí ohun tó o kọ́kọ́ sọ fun un. Ó lè jẹ́ pé ẹ̀rù ló ń bà á. Má gbàgbé pé gbogbo akéde kò rí bákan náà àti pé oríṣiríṣi ọ̀nà tó tọ́ ló wà tá a lè gbà ṣe ohun kan náà.—1 Kọ́r. 12:4-7.
5. Kí la lè sọ tá a bá ń lo ìdánúṣe láti jẹ́ kí akéde tuntun kan mọ́ ohun tó lè sọ?
5 Nígbà míì akéde tuntun náà lè ní kó o sọ àwọn ohun tóun lè sọ níwájú onílé fún òun. Àmọ́, bí kò bá bi ẹ́, lo ìdánúṣe láti ràn án lọ́wọ́. Báwo lo ṣe lè fọgbọ́n ràn án lọ́wọ́? Ohun tí àwọn akéde kan tó ti nírìírí máa ń ṣe ni pé, wọ́n á bi akéde ọ̀hún pé, “Ǹjẹ́ mo lè dá àbá kan fún ẹ?” tàbí “Báwo lo ṣe rí ohun tí mo sọ fún onílé yẹn sí?” Ohun míì tó o tún lè sọ ni pé, “Nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde, ó máa ń ṣòro fún mi láti . . . , àmọ́ ohun tó ràn mí lọ́wọ́ ni. . . .” Nígbà míì ó máa dáa kẹ́ ẹ jọ ṣàyẹ̀wò ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó. Kó má bàa rò pé òun kò ṣe dáadáa rárá, apá kan lára ọ̀nà tó gbà gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ ni kó o sọ̀rọ̀ lé lórí.
6. Ọ̀nà wo ni ‘irin gbà ń pọ́n irin,’ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
6 Irin Máa Ń Pọ́n Irin: Pọ́ọ̀lù gba Tímótì tó jẹ́ ajíhìnrere tó nírìírí níyànjú láti máa fi ara rẹ̀ fún kíkọ́ni, kó sì máa tẹ̀ síwájú. (1 Tím. 4:13, 15) Bó bá tiẹ̀ ti pẹ́ tó o ti ń wàásù, kò yẹ kó o ṣíwọ́ láti máa mú ọnà tó o gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ sunwọ̀n sí i. Máa kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn akéde tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, títí kan àwọn tí kò tíì fi bẹ́ẹ̀ nírìírí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, kó o sì wà lójúfò láti ran àwọn míì lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́, pàápàá jù lọ àwọn ẹni tuntun, kí àwọn náà lè di òjíṣẹ́ ìhìn rere tó mọ ọ̀rọ̀ gbé kalẹ̀.—Òwe 27:17.