Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ June 7
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 7
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 5 ìpínrọ̀ 16 sí 20 àti àpótí tó wà lójú ìwé 55
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 19-21
No. 1: 2 Sámúẹ́lì 19:11-23
No. 2: Ète Ọlọ́run Ni Pé Kí Ilẹ̀ Ayé Jẹ́ Párádísè? (td 25A)
No. 3: Bí Èṣù Ṣe Ń Fọ́ Ojú Àwọn Èèyàn sí Òtítọ́ (2 Kọ́r. 4:4)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Máa Wàásù Lọ́nà Tó Máa Yéni. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 226 sí 229.
10 min: Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí “Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí,” tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù March 2010. Sọ ìrírí tó ń fúnni níṣìírí kan tàbí méjì tẹ́ ẹ ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ní kí akéde kan ṣe àṣefihàn ìrírí kan tẹ́ ẹ ní lẹ́nu àìpẹ́ yìí lágbègbè yín. Ní káwọn ará sọ àwọn ohun tó fani lọ́kàn mọ́ra nínú ìròyìn iṣẹ́ ìsìn kárí ayé, tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù February 2010. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, gba àwọn ará níyànjú pé kí àwọn tó bá lè ka èdè Gẹ̀ẹ́sì ka ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn Yearbook, ti ọdún 2010, kí wọ́n lè jàǹfààní látinú àwọn ìrírí táwọn ará wa ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.
10 min: Oríṣiríṣi Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Wàásù Ìhìn Rere—Bá A Ṣe Lè Máa Ṣiṣẹ́ Ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Tí Wọ́n Ti Ń Sọ Onírúurú Èdè. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 107, ìpínrọ̀ 1 sí 2. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu alábòójútó iṣẹ́ ìsìn. Àwọn ìjọ tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè wo ló mọ̀ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù kan náà? Àwọn ètò wo ni ìjọ yín ti ṣe kẹ́ ẹ lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìjọ yìí láti wàásù fún gbogbo àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù náà lọ́nà tí kò fi ní jẹ́ pé ìpínlẹ̀ ìwàásù táwọn ìjọ kan ti ṣiṣẹ́ ni ìjọ yín á máa tún ṣe?