ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb17 September ojú ìwé 7
  • Kọ́ Wọn Láti Máa Sin Jèhófà Láìyẹsẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kọ́ Wọn Láti Máa Sin Jèhófà Láìyẹsẹ̀
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Apá Kẹwàá: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Bá A Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Ẹni Tuntun Láti Máa Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Bó O Ṣe Lè Dá Àwọn Ẹni Tuntun Lẹ́kọ̀ọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
mwb17 September ojú ìwé 7

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Kọ́ Wọn Láti Máa Sin Jèhófà Láìyẹsẹ̀

Àwọn ohun tá à ń rí fi hàn pé tí àwọn akéde bá tètè bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù déédéé, irú wọn ló máa ń di akéde ògbóṣáṣá. (Owe 22:6; Flp 3:16) Àwọn àbá díẹ̀ rèé nípa bá a ṣe lè ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìpìlẹ̀ tó dára lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù:

  • Gbàrà tí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ti di akéde ni kó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í dá a lẹ́kọ̀ọ́. (km 8/15 1) Jẹ́ kó mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kó máa jáde òde ẹ̀rí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. (Flp 1:10) Máa sọ ohun tó dára gan-an nípa ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. (Flp 4:8) Gbà á níyànjú pé kó bá alábòójútó àwùjọ àtàwọn míì ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí kó bàa lè kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìrírí wọn.​—Owe 1:5; km 10/12 6 ¶3

    Arákùnrin kan ń kọ́ ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde bó ṣe máa múra sílẹ̀ fún òde ẹ̀rí
  • Lẹ́yìn tí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ti ṣèrìbọmi, máa fún un níṣìírí nìṣó, kó o sì máa dá a lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ní pàtàkì tí kò bá tíì ka ìwé Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run tán.​—km 12/13 7

    Arábìnrin kan ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí pẹ̀lú ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde
  • Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó rọrùn ni kó o máa lò nígbà tó o bá ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí pẹ̀lú ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde. Tí akéde náà bá ti lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan, gbóríyìn fún un dáadáa. Kó o sì fún un ní àwọn àbá tó lè mú kó túbọ̀ tẹ̀ síwájú.​—km 5/10 7

    Bàbá kan àti ọmọkùnrin rẹ̀ jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́