Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Ṣèrànwọ́ fún Ẹni Tẹ́ Ẹ Jọ Ṣiṣẹ́ Lóde Ẹ̀rí
Kí Nìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Jésù mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú kéèyàn bá àwọn míì ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí iye wọn jẹ́ àádọ́rin láti lọ wàásù láwọn ibi tóun náà ṣì máa lọ, méjì-méjì ló pín wọn. (Lúùkù 10:1) Tí ẹni méjì bá jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, wọ́n lè ran ara wọn lọ́wọ́ tí ìṣòro kan bá wáyé tàbí tí ọ̀kan nínú wọn ò bá mọ bó ṣe yẹ kó dáhùn ìbéèrè tí onílé béèrè. (Oníw. 4:9, 10) Ọ̀kan nínú wọn lè sọ ìrírí ara rẹ̀ fún ẹni tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè sọ ohun tó máa ran ẹni tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ kó lè di ajíhìnrere tó túbọ̀ jáfáfá. (Òwe 27:17) Bákan náà tí wọ́n bá kúrò níbì kan, kí wọ́n tó kan ilẹ̀kùn ilé tó kàn ó lè sọ̀rọ̀ tó máa gbé ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ró, kó sì fún un níṣìírí.—Fílí. 4:8.
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Tí ìwọ àti ẹnì kan bá jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá parí iṣẹ́, sọ ohun tó ṣe tàbí tó sọ tó ràn ẹ́ lọ́wọ́ fún un.