Máa Ṣèrànwọ́ fún Ẹni Tẹ́ Ẹ Jọ Ń Wàásù Lóde Ẹ̀rí
1. Àǹfààní wo ló wà nínú bíbá ẹlòmíì ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí?
1 Nígbà kan, Jésù rán àádọ́rin [70] ọmọ ẹ̀yìn jáde láti wàásù, ó sì “rán wọn jáde ní méjìméjì.” (Lúùkù 10:1) Ó dájú pé ohun tí Jésù ṣe yìí jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti ran ara wọn lọ́wọ́, kí wọ́n sì fún ara wọn níṣìírí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ nígbà tá a bá ń wàásù pẹ̀lú akéde míì lóde ẹ̀rí?
2. Kí ló yẹ ká ṣe nígbà tí ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí bá ń wàásù, kí sì nìdí?
2 Nípa Fífetí Sílẹ̀: Fetí sílẹ̀ dáadáa nígbà tí ẹni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ bá ń wàásù. (Ják. 1:19) Bó bá ń ka Bíbélì, máa fojú bá a lọ nínú Bíbélì tìrẹ. Máa wojú ẹni tó ń sọ̀rọ̀, ì báà jẹ́ onílé tàbí ẹni tẹ́ ẹ jọ ń wàásù. Tó o bá pàfiyèsí sí ìjíròrò náà dáadáa, ìyẹn lè jẹ́ kí onílé náà ṣe bákan náà.
3. Ìgbà wo ni ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lè fẹ́ ká dá sí ọ̀rọ̀ tó ń sọ?
3 Nípa Fífòye Mọ Ìgbà Tó Yẹ Kó O Sọ̀rọ̀: Nígbà tí ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ bá ń wàásù, a máa buyì kún un tá a bá jẹ́ kó múpò iwájú nínú ìjíròrò náà. (Róòmù 12:10) Kò ní dáa ká máa já lu ọ̀rọ̀ rẹ̀. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ó gbàgbé ohun tó fẹ́ sọ tàbí pé onílé ta ko ọ̀rọ̀ rẹ̀ tàbí onílé béèrè ohun kan tí ẹnì kejì wa sì ní ká ran òun lọ́wọ́, ṣe ni ká ṣe àfikún sí ohun tí ẹnì kejì wa sọ dípò ká bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò lórí kókó míì. (Òwe 16:23; Oníw. 3:1, 7) Tá a bá dá sí ọ̀rọ̀ náà, ó yẹ ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa bá ohun tí ẹnì kejì wa ń sọ mu.—1 Kọ́r. 14:8.
4. Kí ló máa jẹ́ ká ní ìdùnnú àti àṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
4 Nígbà tí àádọ́rin [70] ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n jáde ní méjì-méjì parí iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n “padà dé pẹ̀lú ìdùnnú.” (Lúùkù 10:17) Inú àwa pẹ̀lú máa dùn, a sì máa ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa bá a ti ń fetí sílẹ̀, tá a sì ń fòye mọ ìgbà tó yẹ ká sọ̀rọ̀ bá a ti ń ṣèrànwọ́ fún ẹni tá a jọ ń wàásù lóde ẹ̀rí.