Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 29
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 29
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 14-15
No. 1: 1 Sámúẹ́lì 14:24-35
No. 2: Àwọn Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Sún Mọ́ Jèhófà (Ják. 4:8)
No. 3: Ṣé Ọjọ́ Oníwákàtí Mẹ́rìnlélógún Làwọn Ọjọ́ Ìṣẹ̀dá? (td 29B)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Sọ ọjọ́ tó kàn tí ìjọ yín máa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn lákànṣe. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tó ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ wo ló ti rí i pé ó gbéṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín? Kí ló máa ń fi sọ́kàn nígbà tó bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò? Ní kó ṣe àṣefihàn ọ̀kan lára àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó máa ń lò.
10 min: Kópa Nínú Iṣẹ́ Wíwá Kiri Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ! Àsọyé tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 95, lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Bá A Ṣe Ń Wá Àwọn Tó Fẹ́ Gbọ́ Rí.”
10 min: “Máa Ṣèrànwọ́ fún Ẹni Tẹ́ Ẹ Jọ Ń Wàásù Lóde Ẹ̀rí.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 178