Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 22
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 22
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 10-13
No. 1: 1 Sámúẹ́lì 10:17-27
No. 2: Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Tòótọ́ Bá Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìṣẹ̀dá Mu (td 29A)
No. 3: Ìdí Tí Ẹfolúṣọ̀n Kò Fi Bá Ẹ̀kọ́ Kristẹni Mu
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀. Fi àwọn ìfilọ̀ tó bá yẹ nípa Ìrántí Ikú Kristi kún un.
15 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Àkànṣe Ilé Ìṣọ́ April 1. Sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tó wà nínú ìwé ìròyìn náà. Ní kí àwọn ará sọ ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ní lọ́kàn láti lò. Ṣe àṣefihàn ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ méjì.
15 min: Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ sí Òtítọ́ Tó Máa Wá Síbi Ìrántí Kristi. Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. Rán àwọn ará létí ojúṣe wọn láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn akéde aláìṣedéédéé àti àwọn àlejò. (Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù March ọdún 2008, ojú ìwé 4.) Ṣe àṣefihàn ṣókí kan. Rán àwọn ará létí pé kí wọ́n ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a ṣètò fún àkókò Ìrántí Ikú Kristi.