Iṣẹ́ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ
1. Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ lórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, kí ni èyí á mú ká ṣe?
1 Kí nìdí tí ètò Ọlọ́run fi ń fún wa níṣìírí láti máa lo àkókò wa, okun wa àti gbogbo ohun tá a ní lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? Ìdí ni pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ! Tá a bá ronú lórí bí iṣẹ́ náà ṣe máa ń nípa lórí àwọn èèyàn tó, èyí á jẹ́ ká túbọ̀ fẹ́ nípìn-ín nínú iṣẹ́ tí a kò ní tún ṣe mọ́ yìí.—Ìṣe 20:24.
2. Ọ̀nà wo ni iṣẹ́ ìwàásù wa gbà ń sọ orúkọ títóbi lọ́lá Jèhófà di mímọ́?
2 Ó Ń Sọ Orúkọ Jèhófà Di Mímọ́: Iṣẹ́ ìwàásù wa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ìjọba Jèhófà lábẹ́ ìdarí Kristi Jésù máa rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn, ó sì máa yanjú gbogbo ìṣòro tó ń bá ìran èèyàn fínra. (Mát. 6:9, 10) Ó ń gbé Jèhófà ga gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ṣoṣo tó lè dá wa sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àìsàn àti ikú. (Aísá. 25:8; 33:24) Torí à ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà, àwọn tó ń kíyè sí ìwà rere àti ìtara wa lè yìn ín lógo. (1 Pét. 2:12) Inú wa dùn gan-an pé à ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kárí ayé!—Sm. 83:18.
3. Àwọn ìbùkún wo làwọn tó bá fetí sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run máa rí gbà?
3 Ó Ń Gba Ẹ̀mí Là: Jèhófà “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pét. 3:9) Àmọ́, tí kò bá sí ẹni tó máa kọ́ wọn, báwo ni àwọn èèyàn ṣe lè mọ ìwà tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́ lójú Jèhófà? (Jónà 4:11; Róòmù 10:13-15) Nígbà táwọn èèyàn bá tẹ́wọ́ gba ìhìn rere, tí wọ́n sì jáwọ́ nínú àwọn àṣà tó lè pa wọ́n lára, ìgbé ayé wọn máa ń sunwọ̀n sí i. (Míkà 4:1-4) Láfikún sí i, wọ́n á wá ní ìrètí aláyọ̀, ìyẹn wíwà láàyè títí láé. Bá a ṣe ń fìtara wàásù tá a sì ń kọ́ni, a máa gba ara wa àtàwọn tó ń gbọ́ wa là. (1 Tím. 4:16) Àǹfààní ńlá gbáà la ní láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ yìí!
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fìtara kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?
4 Láìpẹ́ ìpọ́njú ńlá máa mú òpin bá ayé aláìṣòdodo yìí lójijì. Àwọn tó bá ṣe ìfẹ́ Jèhófà ló máa yè bọ́. Ó dájú nígbà náà pé iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn ni iṣẹ́ kánjúkánjú, tó ṣe pàtàkì tó sì ṣàǹfààní jù lọ tá à ń ṣe lónìí. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa kà á sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé wa!—Mát. 6:33.