Sísọ Orúkọ Ọlọ́run Di Mímọ̀
1. Ipa wo ní mímọ orúkọ Ọlọ́run lè ní lórí àwọn èèyàn?
1 Báwo ló ṣe rí lára rẹ nígbà tí o kọ́kọ́ gbọ́ orúkọ Ọlọ́run? Ìṣarasíhùwà ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń dà bíi ti obìnrin kan tó sọ pé: “Nígbà tí mo kọ́kọ́ rí orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì, mo sunkún. Ó wú mi lórí gan-an nígbà tí mo gbọ́ pé mo lè mọ orúkọ Ọlọ́run kí n sì máa lò ó.” Ní ti obìnrin yìí, mímọ̀ tó mọ orúkọ Ọlọ́run jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì sí mímọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan, kí ó sì lè ní àjọṣe pẹ̀lú rẹ̀.
2. Kì nìdí tó fi jẹ́ kánjúkánjú fún wa láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa Jèhófà?
2 Kì Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Sọ Ọ́ Di Mímọ̀? Mímọ orúkọ Ọlọ́run kan kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀, ète rẹ̀, àtàwọn ìṣe rẹ̀. A tún gbọ́dọ̀ mọ orúkọ Ọlọ́run ká tó lè rí ìgbàlà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.” Àmọ́, Pọ́ọ̀lù sọ pé, “báwo ni wọn yóò ṣe ké [pè é]” láìjẹ́ pé àwọn èèyàn kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kí wọn sì lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀? Nítorí èyí, ó jẹ́ kánjúkánjú fún àwọn Kristẹni láti jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn mọ orúkọ Ọlọ́run àti gbogbo ohun tí orúkọ náà dúró fún. (Róòmù 10:13, 14) Àmọ́ ṣá, ìdí kan wà tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ tá a fi gbọ́dọ̀ sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ̀.
3. Kí ni olórí ìdí tí a fi ń wàásù?
3 Ní àwọn ọdún 1920, àwọn èèyàn Ọlọ́run lóye ọ̀ràn àríyànjiyàn tó dójú kọ aráyé nínú Ìwé Mímọ́, ọ̀ràn náà jẹ mọ́ ìdáláre ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ àti ìsọdimímọ́ orúkọ rẹ̀. Kí Jèhófà tó pa àwọn ẹni ibi run láti lè mú ẹ̀gàn tí wọ́n ti kó bá orúkọ rẹ̀ kúrò, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ sọ òtítọ́ nípa rẹ̀ “di mímọ̀ ní gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Aísá. 12:4, 5; Ìsík. 38:23) Nítorí èyí, olórí ìdí tí a fi ń wàásù jẹ́ láti yin Jèhófà ní gbangba kí a sì sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ lójú aráyé. (Héb. 13:15) Ìfẹ́ tí a ní fún Ọlọ́run àti àwọn aládùúgbò wa yóò sún wa láti kópa ní kíkún nínú iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wa yìí.
4. Báwo láwọn èèyàn ṣe mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ orúkọ Ọlọ́run?
4 “Ènìyàn Kan fún Orúkọ Rẹ̀”: Ní ọdún 1931, a tẹ́wọ́ gba orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Aísá. 43:10) Látìgbà náà wá, àwọn èèyàn Ọlọ́run ti sọ orúkọ àtọ̀runwá náà di mímọ̀ débi pé ìwé Proclaimers sọ ní ojú ìwé 124 pé: “Káàkiri orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé, kíá láwọn èèyàn máa ń dá ẹnikẹ́ni tó bá ń lo orúkọ Jèhófà fàlàlà mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Ṣé bí wọ́n ṣe ń dá ìwọ náà mọ̀ nìyẹn? Ó yẹ kí ẹ̀mí ìmoore tá a ní fún Jèhófà sún wa láti “máa fi ìbùkún fún orúkọ [rẹ̀],” kí a sì máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní gbogbo àkókò tó bá yẹ.—Sm. 20:7; 145:1, 2, 7.
5. Báwo ni ìwà wa ṣe kan jíjẹ́ tá à ń jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run?
5 Gẹ́gẹ́ bí “ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀,” ó yẹ ká rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà rẹ̀. (Ìṣe 15:14; 2 Tím. 2:19) Nǹkan táwọn èèyàn sábà máa ń kọ́kọ́ kíyè sí nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìwà ọmọlúwàbí tí à ń hù. (1 Pét. 2:12) A ò ní fẹ́ tàbùkù sí orúkọ Ọlọ́run nípa ríré àwọn ìlànà rẹ̀ kọjá tàbí nípa fífi ìjọsìn rẹ̀ sí ipò kejì nínú ìgbésí ayé wa. (Léf. 22:31, 32; Mál. 1:6-8, 12-14) Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí ọ̀nà tí a gbà ń gbé ìgbésí ayé wa fi hàn pé a ka àǹfààní tá a ní láti jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run sí iyebíye.
6. Àǹfààní wo ni a lè máa gbádùn nísinsìnyí àti títí láé?
6 Lónìí, ọ̀rọ̀ Jèhófà ń ní ìmúṣẹ lójú wa kòrókòró, ó sọ pé: “Láti yíyọ oòrùn àní dé wíwọ̀ rẹ̀, orúkọ mi yóò tóbi láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mál. 1:11) Ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti máa sọ òtítọ́ nípa Jèhófà di mímọ̀ kí a sì máa “fi ìbùkún fún orúkọ mímọ́ rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”—Sm. 145:21.