Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Iná Ìtara Yín fún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Jó Rẹ̀yìn
1 Láti ọdún 1992, ó ju bílíọ̀nù kan wákàtí lọ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé lọ́dọọdún, tá a sì ń sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn. Ẹ ò rí i bí ayọ̀ wa ti pọ̀ tó láti ṣe ìwọ̀nba ohun tá a lè ṣe nínú àṣeyọrí tó kàmàmà yìí!—Mát. 28:19, 20.
2 Kò sí àníàní pé Jèhófà ló yẹ ká fọpẹ́ fún, torí pé òun ló ń mú ká ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láwọn “àkókò lílekoko” yìí. (2 Tím. 3:1) Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ máa bá a lọ ní fífi ìtara ṣe iṣẹ́ pàtàkì yìí?
3 Ohun Tó Ń Jẹ́ Ká Nítara: Ìfẹ́ àtọkànwá tá a ní sí Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wa àti ìpinnu wa láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ ló ń mú ká máa fìtara ṣe iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 22:37-39; 1 Jòh. 5:3) Ìfẹ́ tá a ní ló ń jẹ́ ká lè yááfì àwọn nǹkan kan ká bàa lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù.—Lúùkù 9:23.
4 Ẹ Sapá Kí Ìtara Yín Má Bàa Jó Rẹ̀yìn: Gbogbo ọ̀nà ni elénìní wa, Èṣù, ń gbà láti rí i pé òun pa iná ìtara tá a ní fún iṣẹ́ ìwàásù. Ìrònú nípa àwọn tí ò fìfẹ́ hàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, ipò nǹkan tí ò fara rọ, ọ̀ràn àtijẹ àtimu àti ara wa tó túbọ̀ ń di hẹ́gẹhẹ̀gẹ lójoojúmọ́ wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ohun tí Èṣù ń lò láti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa.
5 Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ sapá gidigidi kí iná ìtara wa lè máa jó fòfò. Ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kí “ìfẹ́ [tá a] ní ní àkọ́kọ́” máa wà lọ́kàn wa. Ìyẹn ni pé ká máa ka Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ká sì máa ṣàṣàrò lórí rẹ̀. Ká máa lo gbogbo ohun tí Jèhófà ń tipasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pèsè kí ìgbàgbọ́ wa nínú Rẹ̀ má bàa ṣákìí.—Ìṣí. 2:4; Mát. 24:45; Sm. 119:97.
6 Báwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ̀, Jèhófà máa tó pa àwọn ẹni búburú run. (2 Pét. 2:3; 3:10) Níwọ̀n bá a ti mọ̀ bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká sapá gidigidi kí iná ìtara wa lè máa jó ròkè lálá bá a ti ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn, tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí kárí ayé!