Ṣé Wàá Jẹ́ Onítara Bíi Ti Jèhófà àti Jésù Nígbà Ìrántí Ikú Kristi Tó Ń Bọ̀ Yìí?
1. Kí ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá lákànṣe láti ṣe nígbà Ìrántí Ikú Kristi?
1 Jèhófà máa ń lo ìtara láti mú kí ète rẹ̀ ṣẹ. Nígbà tí Aísáyà 9:7 ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run yóò mú wá, ó ní: “Ìtara Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ṣe èyí.” Bákan náà, nígbà tí Ọmọ Ọlọ́run ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó lo ìtara tó pọ̀ gan-an nínú ìjọsìn tòótọ́. (Jòh. 2:13-17; 4:34) Lọ́dọọdún, nígbà Ìrántí Ikú Kristi, ọ̀kẹ́ àìmọye akéde kárí ayé máa ń sapá lákànṣe láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìtara Jèhófà àti Jésù nípa ṣíṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ṣé ìwọ náà máa wà lára wọn?
2. Kí ni ìtara tá a ní yóò mú ká ṣe bẹ̀rẹ̀ láti March 7?
2 Ìpolongo Nígbà Ìrántí Ikú Kristi: Ọjọ́ Saturday, March 7 la ó bẹ̀rẹ̀ ìpolongo Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún yìí. Ìsinsìnyí ni kó o ti máa wéwèé bí wàá ṣe fi ìtara kópa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Inú àwọn ará máa dùn bí wọ́n ṣe ń fi ìtara pín ìwé ìkésíni yìí kárí àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe láti ké sí àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ìpadàbẹ̀wò wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, ìbátan wa àtàwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ wa. A lè fún wọn ní ìwé ìkésíni tàbí ká lo ìkànnì jw.org/yo.
3. Báwo la ṣe lè mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i ní oṣù March àti April?
3 Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́: Ìtara tá a ní yóò tún jẹ́ ká mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ lára wa yóò láǹfààní láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù March àti April, torí pé a lè yàn láti ròyìn ọgbọ̀n [30] wákàtí tá a bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Nígbà ìjọsìn ìdílé tàbí ìgbà ìdákẹ́kọ̀ọ́ yín, ẹ fi ọ̀rọ̀ náà sádùúrà, kí ẹ sì sọ̀rọ̀ nípa bí ẹ ṣe fẹ́ mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yín gbòòrò sí i. (Òwe 15:22) Àwọn ẹlòmíì náà á fi ìtara kópa nínú ìpolongo yìí tí wọ́n bá rí bí o ṣe ń fìtara ṣe é. Tí o bá ṣe àwọn àyípadà tó yẹ kó o lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ńṣe lò ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìtara Jésù.—Máàkù 6:31-34.
4. Àwọn ìbùkún wo la máa rí tí a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìtara Jèhófà àti ti Jésù?
4 Ọ̀pọ̀ ìbùkún la máa rí tí a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìtara Jèhófà àti ti Jésù nígbà Ìrántí Ikú Kristi tó ń bọ̀ yìí. A ó wàásù fáwọn èèyàn púpọ̀ sí i ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. A ó ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tó máa ń wá látinú sísin Jèhófà àti fífún àwọn ẹlòmíì ní nǹkan. (Ìṣe 20:35) Ní pàtàkì jù lọ, a ó mú inú Ọlọ́run wa onítara àti Ọmọ rẹ̀ dùn.