ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb23 January ojú ìwé 16
  • Àwọn Nǹkan Wo Lo Lè Fi Ṣe Àfojúsùn Rẹ Lásìkò Ìrántí Ikú Kristi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Nǹkan Wo Lo Lè Fi Ṣe Àfojúsùn Rẹ Lásìkò Ìrántí Ikú Kristi?
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ò Ń Múra Sílẹ̀ De Ọjọ́ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ́dún?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Jèhófà Máa Ń Bù Kún Wa Tá A Bá Ṣe Ìrántí Ikú Kristi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ṣe Ohun Tó Máa Mú Kó O Láyọ̀ Lákòókò Ìrántí Ikú Kristi Tó Ń Bọ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Àkókò Ìrántí Ikú Kristi Máa Ń Jẹ́ Ká Lè Fi Kún Ìgbòkègbodò Wa!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
mwb23 January ojú ìwé 16

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Nǹkan Wo Lo Lè Fi Ṣe Àfojúsùn Rẹ Lásìkò Ìrántí Ikú Kristi?

Lọ́dọọdún, àwa èèyàn Jèhófà máa ń fojú sọ́nà láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi pa pọ̀. Láwọn ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú àtèyí tó tẹ̀ lé e, a máa ń lo àǹfààní yẹn láti yin Jèhófà ká sì dúpẹ́ fún ẹ̀bùn ìràpadà tó fún wa. (Ef 1:3, 7) Bí àpẹẹrẹ, a máa ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Láwọn oṣù March tàbí April ọ̀pọ̀ máa ń ṣètò àkókò wọn láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, wọ́n á sì láǹfààní láti ròyìn ọgbọ̀n (30) tàbí àádọ́ta (50) wákátì. Ṣé o lè fi kún àkókò tó ò ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lákòókò Ìrántí Ikú Kristi yìí? Báwo lo ṣe lè ṣe é?

Òótọ́ kan ni pé, a lè ṣàṣeyọrí tá a bá múra sílẹ̀. (Owe 21:5) Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká ti bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ bí ọjọ́ náà ṣe ń sún mọ́. Ronú nípa bó o ṣe lè fi kún àkókò tó o máa lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lásìkò Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì pinnu ohun tó o lè ṣe kí ọwọ́ rẹ lè tẹ àfojúsùn náà. Lẹ́yìn náà, bẹ Jèhófà pé kó bù kún ìsapá ẹ.—1Jo 5:14, 15.

Ṣé o lè ronú àwọn ọ̀nà míì tó o lè gbà ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ lákòókò Ìrántí Ikú Kristi yìí?

Àfojúsùn

Ohun tí mo lè ṣe kí ọwọ́ mi lè tẹ àwọn àfojúsùn mi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́