Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 16
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 16
Orin 80 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 20 ìpínrọ̀ 8 sí 15 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 15-18 (8 min.)
No. 1: Àwọn Onídàájọ́ 16:13-24 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?—igw ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 1 sí 4 (5 min.)
No. 3: Àwọn Ọ̀nà Tí Ọlọ́run Gbà Fi Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Hàn—1 Pét. 4:10 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Ẹ Jẹ́ “Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà”!—Títù 2:14.
15 min: Múra Sílẹ̀ Láti Fi Ìtara Polongo Ìhìn Rere. Ìjíròrò. Kí nìdí tí gbígbàdúrà sí Jèhófà fi jẹ́ ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nínú mímúra iṣẹ́ òjíṣẹ́ sílẹ̀? (Sm. 143:10; Ìṣe 4:31) Ní àfikún sí àdúrà gbígbà, kí ló tún yẹ ka ṣe? (Ẹ́sírà 7:10) Lẹ́yìn tá a bá ti múra ara wa sílẹ̀ nípa tẹ̀mí, àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe nípa àwọn ìtẹ̀jáde tá a fẹ́ lò àti àpò òde ẹ̀rí wa? Ipa rere wo ni ìmúrasílẹ̀ máa ń ní lórí wa? (Wo Ilé Ìṣọ́, July 15, 2008, ojú ìwé 9, ìpínrọ̀ 9.) Báwo lo ṣe máa ń múra iṣẹ́ òjíṣẹ́ sílẹ̀? Ní kí akéde kan ṣe àṣefihàn bó ṣe máa ń múra òde ẹ̀rí sílẹ̀, kó ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú, àwọn ìwé ìròyìn tàbí àwọn ìwé pẹlẹbẹ tó fẹ́ lò lóde ẹ̀rí. Lẹ́yìn náà, kó to àpò òde ẹ̀rí rẹ̀, kó sì ríi dájú pé ẹ̀rọ̀ alágbèéká rẹ̀ ṣíṣẹ́ dáadáa. Tẹnu mọ́ ọn fún àwọn ará pé ó yẹ kí gbogbo wa máa múra sílẹ̀ dáadáa tá a bá ń lọ sóde ẹ̀rí. (2 Tím. 3:17)
15 min: “Ṣé Wàá Jẹ́ Onítara Bíi Ti Jèhófà àti Jésù Nígbà Ìrántí Ikú Kristi Tó Ń Bọ̀ Yìí?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fún àwọn ará ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì jíròrò ohun tó wà nínú rẹ̀. Ní kí akéde kan fi ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé 4 ṣe àṣefihàn kan.
Orin 30 àti Àdúrà