Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 23
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 23
Orin 21 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 20 ìpínrọ̀ 16 sí 21 àti àpótí tó wà lójú ìwé 207 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 19-21 (8 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Ẹ Jẹ́ “Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà”!—Títù 2:14.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Jẹ́ Onítara fún Ìjọsìn Tòótọ́ Bíi Ti Jésù. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ May 15, 2013, ojú ìwé 8, ìpínrọ̀ 2, àti Ilé Ìṣọ́ December 15, 2010, ojú ìwé 9 sí 11, ìpínrọ̀ 12 sí 16. Tẹnu mọ́ bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe jẹ́ “iṣẹ́ àtàtà” tí a láǹfààní láti ṣe. (Títù 2:14) Mẹ́nu kan bí mímọ̀ tá a mọ òtítọ́ ṣe ń jẹ́ ká lè máa fi ìtara wàásù ìhìn rere ká sì máa darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Gbóríyìn fún àwọn ará fún bí wọ́n ṣe lo ìtara lẹ́nu iṣẹ́ àtàtà.
10 min: “Máa Fi Ìtara Polongo Òtítọ́ Nípa Jésù.” Ìjíròrò. Ní kí akéde kan ṣe àṣefihàn “Àpẹẹrẹ 1” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 2014, lójú ìwé 8 ìpínrọ̀ 8, kí akéde náà sì lo àpèjúwe tó wà ní ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 13.
Orin 5 àti Àdúrà