Máa Fi Ìtara Polongo Òtítọ́ Nípa Jésù
Ìtara wa á túbọ̀ pọ̀ sí i tá a bá mọ bí a ṣe lè sọ òtítọ́ nípa Jésù fún àwọn èèyàn. Jésù ni òkúta ìpìlẹ̀ igun ilé tí a kọ́ ìsìn tòótọ́ lé lórí. (Éfé. 2:20) A ò lè ní ìrètí ìyè ọjọ́ iwájú láìsí ti Jésù. (Ìṣe 4:12) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo èèyàn mọ ipa tí Jésù kó nínú mímú ète Ọlọ́run ṣẹ. Wọ́n ti fi àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Bíbélì mu ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà. Ó sì bani nínú jẹ́ pé wọ́n lè má nípìn-ín nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì fún àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù. Ìtara tá a ní fún òtítọ́ yóò mú ká ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ òtítọ́ nípa ẹni tí Jésù jẹ́, bó ṣe jẹ́ sí Ọlọ́run àti ipa tó ń kó nínú ète Ọlọ́run. Ṣé wàá fi ìtara polongo òtítọ́ nípa Jésù nígbà Ìrántí Ikú Kristi tó ń bọ̀ yìí?