Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní February 23, 2015.
Báwo ni àwọn ìlú ààbò lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ ṣe yàtọ̀ sí ibi ààbò àwọn kèfèrí tó wà fún àwọn ọ̀daràn tó sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá wọn? (Jóṣ. 20:2, 3) [Jan. 5, w10 11/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 4 sí 6]
Kí nìdí tí Jóṣúà fi fi ìdánilójú sọ ọ̀rọ̀ tó wà ní Jóṣúà 23:14, kí sì nìdí tí àwa náà fi lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú àwọn ìlérí Jèhófà? [Jan. 12, w07 11/1 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 19]
Nígbà tí wọ́n pín ilẹ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí nìdí tó fi jẹ́ pé ẹ̀yà Júdà ni wọ́n kọ́kọ́ sọ fún pé kó lọ máa gbé lórí ilẹ̀ tirẹ̀? (Oníd. 1:2, 4) [Jan. 19, w05 1/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 5]
Kí nìdí tí Bárákì fi sọ pé dandan ni kí Dèbórà tó jẹ́ wòlíì obìnrin bá òun lọ sójú ogun? (Oníd. 4:8) [Jan. 19, w05 1/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 4]
Kí ni orúkọ tí Gídíónì fi pe pẹpẹ tó mọ fi hàn, ẹ̀kọ́ wo nìyẹn sì kọ́ wa? (Oníd. 6:23, 24) [Jan. 26, w14 2/15 ojú ìwé 22 àti 23 ìpínrọ̀ 9]
Kí la rí kọ́ látinú bí Gídíónì ṣe fún àwọn ẹ̀yà Éfúráímù tó fẹ́ bá a ṣe aáwọ̀ lésì? (Oníd. 8:1-3) [Feb. 2, w05 7/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 4]
Nígbà tí Jẹ́fútà ń jẹ́jẹ̀ẹ́, ṣé èèyàn ló ní lọ́kàn láti fi rúbọ? (Oníd. 11:30, 31) [Feb. 9, w05 1/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1]
Gẹ́gẹ́ bí Àwọn Onídàájọ́ 11:35-37 ṣe sọ, kí ló jẹ́ kí ọmọbìnrin Jẹ́fútà mú ẹ̀jẹ́ bàbá rẹ̀ ṣẹ? [Feb. 9, w11 12/15 ojú ìwé 20 àti 21 ìpínrọ̀ 15 àti 16]
Nígbà tí kò sí ọba kankan ní Ísírẹ́lì ‘ti olúkúlùkù ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà ní ojú tirẹ̀,’ ǹjẹ́ èyí dá wàhálà kankan sílẹ̀? Ṣàlàyé. (Oníd. 17:6) [Feb. 16, w05 1/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 7]
Ẹ̀kọ́ wo nípa bó ṣe yẹ ká tẹra mọ́ àdúrà gbígbà la rí kọ́ nínú ìtàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì oníwàkiwà ṣẹ́gun lẹ́ẹ̀mejì? (Oníd. 20:14-25) [Feb. 23, w11 9/15 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 1 sí 4]