Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 2
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 2
Orin 5 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 21 ìpínrọ̀ 1 sí 8 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Rúùtù 1-4 (8 min.)
No. 1: Rúùtù 3:14–4:6 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ohun Tó Túmọ̀ Sí Láti Fún Jèhófà Ọlọ́run Ní Ìjọsìn Tá A Yà Sọ́tọ̀ Gédégbé—Ẹ́kís. 20:5 (5 min.)
No. 3: Kristi Ọba Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ àti Agbára—igw ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 4 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Ẹ Jẹ́ “Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà”!—Títù 2:14
10 min: Fi Àwọn Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù March. Ìjíròrò. Kọ́kọ́ fi àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé yìí ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Fún gbogbo àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n ka àwọn ìwé ìròyìn náà dáadáa.
10 min: “Ẹ Jẹ́ Ká Máa Ru Ẹnì Kìíní-Kejì Wa Sókè Ká Lè Jẹ́ Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà.” Ìjíròrò. Sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe tẹnu mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí láwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tá a ṣe lóṣù February.
10 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí? Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní nígbà tí wọ́n lo àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fi Fóònù Wàásù.” Tá a bá rí àwọn tó ti fi fóònù wàásù, ní kí wọ́n sọ bí wọ́n ṣe lò ó.
Orin tuntun “Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ” àti Àdúrà
Ìránnilétí: Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kọ́kọ́ gbọ́ orin yìí lẹ́ẹ̀kan. Lẹ́yìn náà, kí àwọn ará kọ orin tuntun yìí.