ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/09 ojú ìwé 2
  • Jẹ́ Kí “Iná Ẹ̀mí Máa Jó Nínú” Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Kí “Iná Ẹ̀mí Máa Jó Nínú” Rẹ
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Iná Ìtara Yín fún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Jó Rẹ̀yìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Ṣé Wàá Jẹ́ Onítara Bíi Ti Jèhófà àti Jésù Nígbà Ìrántí Ikú Kristi Tó Ń Bọ̀ Yìí?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Máa Fi Ìháragàgà Polongo Ìhìn Rere Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ǹjẹ́ O Ní Ìtara Fún “Iṣẹ́ Àtàtà”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
km 11/09 ojú ìwé 2

Jẹ́ Kí “Iná Ẹ̀mí Máa Jó Nínú” Rẹ

1. Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa?

1 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, kò sí apá kankan nínú iṣẹ́ ìsìn wa tó yẹ ká pa tì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì rọ̀ wá pé ká jẹ́ “kí iná ẹ̀mí máa jó” nínú wa ká sì “máa sìnrú fún Jèhófà.” (Róòmù 12:11) Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú kí ìtara wa dín kù lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìtara wa fún iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run máa “rú sókè bí iná?”— 2 Tím. 1:6, 7.

2. Báwo ni ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lè mú ká jẹ́ onítara lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

2 Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: Bí ẹnì kan bá fẹ́ jẹ́ ọ̀jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, ó gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run, kí ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn ṣinṣin. (Sm. 119:97) Bá a bá kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣíṣeyebíye nígbà tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí máa ń ru ọkàn wa sókè ó sì máa ń mú kí ìtara wa pọ̀ sí i. Ìfẹ́ tá a ní sí Olùpèsè irú ẹ̀kọ́ òtítọ́ bẹ́ẹ̀ àti bó ṣe ń wù wá láti lọ wàásù ìhìn rere fáwọn ẹlòmíì ń mú ká máa yin Ọlọ́run ká sì máa kéde orúkọ rẹ̀. (Heb. 13:15) Kò sí àníàní pé tá a bá ń fìtara wàásù ìhìn rere, ńṣe ni èyí ń fi hàn pé a mọ bó ti ṣe pàtàkì tó.

3. Báwo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

3 Gbàdúrà fún Ẹ̀mí Ọlọ́run: Bá a bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ́nà tó gbéṣẹ́, a ò lè dá ṣe é ní agbára wa nìkan. Bí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń ṣiṣẹ́ fàlàlà nígbèésí ayé wa, a máa ní ojúlówó ìtara. (1 Pét. 4:11) Bá a bá ń sún mọ́ Orísun ‘agbára gíga,’ ó máa fún wa ní okun tẹ̀mí láti máa fìgboyà jẹ́rìí. (Aísá. 40:26, 29-31) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ko ìṣòro lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó “rí ìrànlọ́wọ́ tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run gbà.” (Ìṣe 26:21, 22) Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà tó ń fúnni lókun lè mú kí iná ìtara tiwa náà máa jó lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, torí náà, ó yẹ ká gbàdúrà fún un.—Lúùkù 11:9-13.

4. Kí ló lè jẹ́ àbájáde rẹ̀ bí iná ìtara wa bá ń jó, àmọ́ kí la gbọ́dọ̀ fi kún ìtara wa?

4 Bí iná ìtara wa bá ń jó bá a ṣe ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run, èyí sábà máa ń mú káwọn ará wa yòókù túbọ̀ ní ìtara. (2 Kọ́r. 9:2) Tá a bá ń fi ìtara àti ìdánilójú sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àwọn èèyàn sábà máa ń fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Àmọ́ bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ fi ọgbọ́n àti ìwà tútù kún ìtara wa. (Títù 3:2) Nígbà gbogbo, ká máa rí i dájú pé à ń bọ̀wọ̀ fún àwọn tá à ń wàásù fún, ká sì máa rántí pé wọ́n ní òmìnira láti yan ohun tí wọ́n bá fẹ́.

5. Ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Ọlọ́run mí sí wo ló yẹ ká sapá láti máa fi sílò?

5 Ǹjẹ́ “kí iná ẹ̀mí máa jó” nínú wa, gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká mú ìtara wa pọ̀ sí i nípa ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àdúrà àtọkànwá sí Jèhófà, ẹni tó lè fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tó lágbára gan-an. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ó lè máa fìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa pẹ̀lú “ẹ̀mí mímọ́ àti ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó lágbára.”—1 Tẹs. 1:5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́