Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 16
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 16
Orin 62
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv orí 12 ìpínrọ̀ 15 sí 22, àpótí tó wà lójú ìwé 140
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Diutarónómì 23-27
No. 1: Diutarónómì 25:1-16
No. 2: Àwọn Ọmọdé Tó Mú Inú Ọlọ́run Dùn (lr orí 41)
No. 3: Àwọn Nǹkan Wo Ló Yẹ Ká Kà sí Mímọ́?
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 146
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Lo Ìfòyemọ̀ Kó O sì Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn. Àsọyé tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 258, ìpínrọ̀ 1, sí ojú ìwé 259, ìpínrọ̀ 3.
10 min: Pe Àwọn Olùfìfẹ́hàn Wá Sínú Ètò Jèhófà. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 99, ìpínrọ̀ 1 sí 3. Ṣe àṣefihàn kan tó ṣàlàyé ṣókí lórí kókó kan láti ibi tó o ti mú ọ̀rọ̀ rẹ jáde.
10 min: “Jẹ́ Kí ‘Iná Ẹ̀mí Máa Jó Nínú’ Rẹ.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 16