ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 11
ORIN 57 Máa Wàásù fún Onírúurú Èèyàn
Máa Fìtara Wàásù Bíi Jésù
“Olúwa . . . rán wọn jáde ṣáájú rẹ̀ ní méjì-méjì sínú gbogbo ìlú àti ibi tí òun fúnra rẹ̀ máa lọ.”—LÚÙKÙ 10:1.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa rí ọ̀nà mẹ́rin tá a lè gbà máa fìtara wàásù bíi Jésù.
1. Kí ni ọ̀kan lára ohun tó mú káwa ìránṣẹ́ Jèhófà yàtọ̀ sáwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni?
Ọ̀KAN lára ohun tó mú káwa ìránṣẹ́ Jèhófà yàtọ̀ sáwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni ni pé a máa ń fìtara wàásù. (Títù 2:14) Àmọ́ nígbà míì, ó lè má rọrùn fún ẹ láti máa fìtara wàásù. Ó lè máa ṣe ìwọ náà bí alàgbà kan tó ń ṣiṣẹ́ kára tó sọ pé, “Nígbà míì, kì í wù mí láti wàásù.”
2. Àwọn nǹkan wo ló lè mú kó ṣòro fún wa láti máa fìtara wàásù nígbà míì?
2 Ó ṣeé ṣe ká máa gbádùn àwọn iṣẹ́ kan nínú ètò Ọlọ́run ju iṣẹ́ ìwàásù lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé tá a bá kọ́ àwọn ilé ètò Ọlọ́run tàbí tá a tún un ṣe, tá a bá ran àwọn ará lọ́wọ́ nígbà àjálù tàbí tá a fún wọn níṣìírí, a tètè máa ń rí àǹfààní tí wọ́n ń rí níbẹ̀, ìyẹn sì máa ń múnú wa dùn gan-an. Ara máa ń tù wá tá a bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará wa torí àlàáfíà wà láàárín wa, a nífẹ̀ẹ́ ara wa, a sì mọ̀ pé wọ́n mọyì ohun tá à ń ṣe fún wọn. Àmọ́, a lè ti máa wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa fún ọ̀pọ̀ ọdún, síbẹ̀ káwọn èèyàn má fi bẹ́ẹ̀ gbọ́rọ̀ wa. Àwọn kan sì lè má fẹ́ gbọ́rọ̀ wa rárá. Bákan náà, bí òpin ṣe ń sún mọ́lé, a mọ̀ pé àwọn èèyàn á máa ta kò wá torí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. (Mát. 10:22) Torí náà, kí lá jẹ́ ká máa fìtara wàásù nìṣó?
3. Àpèjúwe wo ló wà nínú Lúùkù 13:6-9 tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù nítara?
3 Tá a bá gbé àpẹẹrẹ Jésù yẹ̀ wò, àá mọ bá a ṣe lè máa fìtara wàásù. Nígbà tó wà láyé, ìgbà gbogbo ló ń fìtara wàásù. Kódà bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ńṣe ni ìtara Jésù ń pọ̀ sí i. (Ka Lúùkù 13:6-9.) Bíi ti ẹni tó ń rẹ́wọ́ ọ̀gbìn tó sì ti lo ọdún mẹ́ta láti tún igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ṣe bí ò tiẹ̀ sèso kankan, Jésù náà lo nǹkan bí ọdún mẹ́ta láti wàásù fáwọn Júù bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára wọn ò fetí sọ́rọ̀ ẹ̀. Lóòótọ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ò sèso, àmọ́ ẹni tó ń bójú tó o kò jẹ́ kó sú òun. Lọ́nà kan náà, Jésù ò jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn tóun ń wàásù fún sú òun, kò sì yéé wàásù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, kóhun tó ń kọ́ wọn lè yé wọn dáadáa.
4. Àwọn nǹkan mẹ́rin wo la máa kọ́ lára Jésù nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí Jésù ṣe fìtara wàásù pàápàá ní oṣù mẹ́fà tó lò kẹ́yìn láyé. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ “After these things” tó wà ní Lúùkù 10:1 nínú nwtsty-E.) Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó kọ́ àwọn èèyàn tá a sì ń ṣe ohun tó ṣe, àá máa fìtara wàásù. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́rin lára ohun tí Jésù ṣe: (1) Ó gbájú mọ́ ohun tí Jèhófà fẹ́, (2) ó fiyè sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, (3) ó gbára lé Jèhófà àti (4) ó dá a lójú pé àwọn kan máa gbọ́rọ̀ ẹ̀.
Ó GBÁJÚ MỌ́ OHUN TÍ JÈHÓFÀ FẸ́
5. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ lòun gbájú mọ́?
5 Jésù fìtara wàásù “ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run” torí ó mọ̀ pé iṣẹ́ tí Ọlọ́run fẹ́ kóun ṣe nìyẹn. (Lúùkù 4:43) Iṣẹ́ ìwàásù ni Jésù gbájú mọ́. Kódà nígbà tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ ń parí lọ, ó rìnrìn àjò láti “ìlú dé ìlú, láti abúlé dé abúlé,” ó sì ń kọ́ àwọn èèyàn. (Lúùkù 13:22) Bákan náà, ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó pọ̀ lẹ́kọ̀ọ́ káwọn náà lè máa wàásù.—Lúùkù 10:1.
6. Báwo làwọn iṣẹ́ míì tá à ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run ṣe ń ti iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
6 Bákan náà lónìí, iṣẹ́ ìwàásù ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù tí Jèhófà àti Jésù fẹ́ ká ṣe. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Gbogbo iṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run ló ń ti iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, ètò Ọlọ́run máa ń kọ́ àwọn ilé tá à ń lò fún ìjọsìn Jèhófà, àwọn kan sì máa ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì kí iṣẹ́ ìwàásù náà lè máa tẹ̀ síwájú. A máa ń pèsè ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá kára lè tù wọ́n, ìyẹn máa ń jẹ́ kí wọ́n pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù, kí wọ́n sì máa ṣe àwọn nǹkan yòókù nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Tá a bá mọ bí iṣẹ́ ìwàásù ti ṣe pàtàkì tó, tá a sì ń rántí pé òun ni iṣẹ́ pàtàkì tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe, á máa wù wá láti wàásù ní gbogbo ìgbà. Alàgbà kan tó ń jẹ́ János lórílẹ̀-èdè Hungary sọ pé: “Mo máa ń sọ fún ara mi léraléra pé kò síṣẹ́ tí mo lè ṣe nínú ètò Ọlọ́run tó lè rọ́pò iṣẹ́ ìwàásù torí pé iṣẹ́ yẹn ló ṣe pàtàkì jù.”
Lónìí, iṣẹ́ ìwàásù ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù tí Jèhófà àti Jésù fẹ́ ká máa ṣe (Wo ìpínrọ̀ 6)
7. Kí nìdí tí Jèhófà ò fi fẹ́ ká jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù? (1 Tímótì 2:3, 4)
7 Tá a bá ń fojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn wò wọ́n, àá túbọ̀ máa fìtara wàásù. Ó fẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbọ́ ìhìn rere, kí wọ́n sì yí pa dà. (Ka 1 Tímótì 2:3, 4.) Torí náà, ó ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ ká lè túbọ̀ já fáfá bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ tó ń gbẹ̀mí là yìí. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn, a máa rí àwọn àbá tó máa jẹ́ kó rọrùn fún wa láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ká sì sọ wọ́n dọmọ ẹ̀yìn. Tí wọn ò bá wá sin Jèhófà báyìí, wọ́n ṣì lè wá sìn ín kí ìpọ́njú ńlá tó parí. Ohun tá a bá sọ fún wọn báyìí lè mú kí wọ́n wá sin Jèhófà lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ ìyẹn máa ṣeé ṣe tá ò bá jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù.
Ó FIYÈ SÍ ÀWỌN ÀSỌTẸ́LẸ̀ BÍBÉLÌ
8. Báwo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù mọ̀ ṣe mú kó lo àkókò ẹ̀ lọ́nà tó dáa jù?
8 Jésù mọ báwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe máa ṣẹ. Ó mọ̀ pé ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ péré lòun máa fi wàásù. (Dán. 9:26, 27) Ó tún mọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tóun máa kú àti bóun ṣe máa kú. (Lúùkù 18:31-34) Àwọn nǹkan tí Jésù mọ̀ yìí mú kó lo àkókò ẹ̀ lọ́nà tó dáa jù. Torí náà, ó fìtara wàásù kó lè parí iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un.
9. Báwo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe ń jẹ́ ká fìtara wàásù?
9 Tá a bá ń ronú nípa bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan ṣe ń ṣẹ lónìí àtàwọn tó máa ṣẹ láìpẹ́, àá máa fìtara wàásù. A mọ̀ pé àsìkò díẹ̀ ló kù kí ayé burúkú yìí pa run. A tún mọ̀ pé àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí àti ìwà àwọn èèyàn fi hàn pé ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ìkẹyìn ti ń ṣẹ. A rí i pé ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ń figa gbága pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn tó ń tì í lẹ́yìn, ó sì ń mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ. Ìyẹn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọba gúúsù àti ọba àríwá “ní àkókò òpin.” (Dán. 11:40) Bákan náà, a mọ̀ pé ẹsẹ̀ ère tí Dáníẹ́lì 2:43-45 sọ ṣàpẹẹrẹ ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Ó dá wa lójú pé bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí ṣe sọ, láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa pa gbogbo ìjọba èèyàn run, àní kò ní pẹ́ rárá! Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí ṣe ń ṣẹ jẹ́ ká mọ̀ pé òpin ti sún mọ́lé gan-an, ó sì ń jẹ́ ká máa fìtara wàásù.
10. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì míì wo ló ń mú kó wù wá láti máa fìtara wàásù?
10 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká fìtara wàásù nípa ẹ̀. Arábìnrin Carrie tó ń sìn ní Dominican Republic sọ pé: “Àwọn ìlérí àgbàyanu tí Jèhófà ṣe nípa ọjọ́ iwájú máa ń jẹ́ kó wù mí láti wàásù òtítọ́ Bíbélì fáwọn èèyàn.” Ó tún sọ pé: “Bí mo ṣe ń rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn, mo wá rí i pé kì í ṣe èmi nìkan làwọn ìlérí yẹn máa tù nínú, ó máa tu àwọn náà nínú.” Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká rí i pé kò yẹ ká dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù torí Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn. Arábìnrin Leila tó ń gbé Hungary sọ pé: “Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Àìsáyà 11:6-9 máa ń jẹ́ kó wù mí láti wàásù fáwọn tó jọ pé wọn ò ní gbọ́ torí mo mọ̀ pé kò sẹ́ni tí Jèhófà ò lè yí pa dà.” Bákan náà, Arákùnrin Christopher tó ń gbé Zambia sọ pé: “Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Máàkù 13:10 sọ pé a máa wàásù ìhìn rere náà kárí ayé, àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé mo wà lára àwọn tó ń mú kí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ.” Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì wo ló ń mú kó wù ẹ́ láti máa fìtara wàásù?
Ó GBÁRA LÉ JÈHÓFÀ
11. Kí nìdí tó fi yẹ kí Jésù gbára lé Jèhófà kó lè máa fìtara wàásù? (Lúùkù 12:49, 53)
11 Jésù gbára lé Jèhófà kó lè máa fìtara wàásù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó mọ bá a ṣe ń báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó mọ̀ pé ìhìn rere Ìjọba náà máa fa àríyànjiyàn àti àtakò tó le gan-an. (Ka Lúùkù 12:49, 53.) Torí pé Jésù ń wàásù, léraléra làwọn olórí ẹ̀sìn gbìyànjú láti pa á. (Jòh. 8:59; 10:31, 39) Àmọ́ Jésù ò dẹwọ́ torí ó mọ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú òun. Ó sọ pé: “Mi ò dá wà, àmọ́ Baba tó rán mi wà pẹ̀lú mi. . . . Kò pa mí tì lémi nìkan, torí gbogbo ìgbà ni mo máa ń ṣe ohun tó wù ú.”—Jòh. 8:16, 29.
12. Báwo ni Jésù ṣe múra àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sílẹ̀ kí wọ́n lè máa wàásù tí wọ́n bá tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí wọn?
12 Jésù rán àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ létí pé kí wọ́n gbára lé Jèhófà. Léraléra ló fi dá wọn lójú pé Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ táwọn èèyàn bá ṣenúnibíni sí wọn. (Mát. 10:18-20; Lúùkù 12:11, 12) Bákan náà, ó ní kí wọ́n máa ṣọ́ra. (Mát. 10:16; Lúùkù 10:3) Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe fipá mú àwọn tí ò fẹ́ gbọ́rọ̀ wọn. (Lúùkù 10:10, 11) Ó tún sọ fún wọn pé kí wọ́n sá tí wọ́n bá ti ń ṣenúnibíni sí wọn. (Mát. 10:23) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù nítara tó sì fọkàn tán Jèhófà, kò fẹ̀mí ara ẹ̀ wewu.—Jòh. 11:53, 54.
13. Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́?
13 Ọ̀pọ̀ ló ń ta ko iṣẹ́ ìwàásù wa lónìí, torí náà a fẹ́ kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ ka lè máa fìtara wàásù. (Ìfi. 12:17) Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa tì ẹ́ lẹ́yìn? Ronú nípa àdúrà Jésù tó wà ní Jòhánù orí 17. Jésù bẹ Jèhófà pé kó máa dáàbò bo àwọn àpọ́sítélì ẹ̀, Jèhófà sì dáhùn àdúrà yẹn. Ìwé Ìṣe sọ bí Jèhófà ṣe ran àwọn àpọ́sítélì lọ́wọ́ láti máa fìtara wàásù báwọn èèyàn tiẹ̀ ń ta kò wọ́n. Jésù tún bẹ Jèhófà pé kó dáàbò bo àwọn tó bá gba ohun táwọn àpọ́sítélì ń wàásù gbọ́. Ìwọ náà sì wà lára wọn. Jèhófà ṣì ń dáhùn àdúrà Jésù yẹn, torí náà Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó ṣe ran àwọn àpọ́sítélì lọ́wọ́.—Jòh. 17:11, 15, 20.
14. Kí ló mú kó dá wa lójú pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, àá ṣì máa fìtara wàásù? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
14 Kódà tó bá ṣòro láti máa fìtara wàásù bí òpin ṣe ń sún mọ́lé, Jèhófà máa tì wá lẹ́yìn. (Lúùkù 21:12-15) Bíi Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀, a kì í fipá mú àwọn èèyàn láti gbọ́rọ̀ wa, a sì máa ń yẹra fún ohun tó lè fa àríyànjiyàn. Kódà tí ìjọba bá dí iṣẹ́ ìwàásù wa lọ́wọ́, àwọn ará wa ṣì máa ń wàásù ìhìn rere náà torí pé Jèhófà ni wọ́n gbára lé kì í ṣe ara wọn. Bí Jèhófà ṣe fún àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ lókun láti máa wàásù, ó máa ń fún àwa náà lókun lónìí ká lè máa “ṣe iṣẹ́ ìwàásù láìkù síbì kan” títí dìgbà tó máa sọ pé ó tó. (2 Tím. 4:17) Torí náà, ó dájú pé tó o bá gbára lé Jèhófà, wàá máa fìtara wàásù nìṣó.
Kódà tí ìjọba bá dí iṣẹ́ wa lọ́wọ́, àwọn ará tó nítara ṣì máa ń wá bí wọ́n ṣe máa wàásù (Wo ìpínrọ̀ 14)a
Ó DÁ A LÓJÚ PÉ ÀWỌN KAN MÁA GBỌ́
15. Báwo la ṣe mọ̀ pé ó dá Jésù lójú pé àwọn èèyàn máa gbọ́rọ̀ ẹ̀?
15 Ó dá Jésù lójú pé àwọn kan máa gbọ́rọ̀ ẹ̀. Ìyẹn ló mú kó máa fìtara wàásù. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọdún 30 S.K. ń parí lọ, Jésù rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ gbọ́rọ̀ òun, torí náà ó fi wọ́n wé pápá tó ti tó kórè. (Jòh. 4:35) Nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn ìyẹn, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Ìkórè pọ̀.” (Mát. 9:37, 38) Lẹ́yìn náà ó tún sọ pé: “Ìkórè pọ̀ . . . Ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè pé kó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde láti bá a kórè.” (Lúùkù 10:2) Ọkàn Jésù balẹ̀ pé àwọn èèyàn máa gbọ́ ìhìn rere, inú ẹ̀ sì dùn nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.—Lúùkù 10:21.
16. Báwo làwọn àpèjúwe Jésù ṣe jẹ́ ká rí i pé àwọn èèyàn máa gbọ́ ìwàásù? (Lúùkù 13:18-21) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ mọ̀ pé àwọn èèyàn máa gbọ́rọ̀ wọn, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n máa fìtara wàásù. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa méjì lára àwọn àpèjúwe tó ṣe. (Ka Lúùkù 13:18-21.) Jésù fi hóró músítádì kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa gbọ́rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, kò sì sẹ́ni tó máa lè dá a dúró. Ó tún fi ìwúkàrà wé bí ìhìn rere Ìjọba náà ṣe máa délé dóko, tó sì máa mú káwọn èèyàn ṣe ìyípadà táwọn ẹlòmíì lè má tètè rí. Àwọn àpèjúwe tí Jésù ṣe yìí jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ rí i pé wọ́n máa ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wọn.
Bíi Jésù, àwa náà gbà pé àwọn kan ṣì máa gbọ́ ìwàásù (Wo ìpínrọ̀ 16)
17. Àwọn nǹkan wo ni ò ní jẹ́ kíṣẹ́ ìwàásù sú wa?
17 Tá a bá ronú lórí bí ìhìn rere ṣe ń ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ lónìí, àá túbọ̀ máa fìtara wàásù. Lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló ń wá sí Ìrántí Ikú Kristi, a sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ń ṣèrìbọmi, táwọn náà sì ń wàásù. A ò mọ iye àwọn tó ṣì máa gbọ́ ìwàásù wa, àmọ́ a mọ̀ pé Jèhófà ń kó ogunlọ́gọ̀ èèyàn jọ, wọ́n sì máa la ìpọ́njú ńlá já. (Ìfi. 7:9, 14) Ọ̀gá ìkórè náà mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì máa gbọ́ ìhìn rere, torí náà a ò ní jẹ́ kíṣẹ́ náà sú wa.
18. Kí la fẹ́ káwọn èèyàn máa rí bá a ṣe ń wàásù?
18 Àwọn èèyàn dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù mọ̀ torí pé wọ́n máa ń fìtara wàásù. Nígbà táwọn èèyàn rí bí ọ̀rọ̀ ṣe dá lẹ́nu àwọn àpọ́sítélì, wọ́n “rántí pé wọ́n ti máa ń wà pẹ̀lú Jésù.” (Ìṣe 4:13) Torí náà, báwọn èèyàn ṣe ń rí wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ẹ jẹ́ kí wọ́n máa rí i pé àwa náà nítara bíi Jésù.
ORIN 58 À Ń Wá Àwọn Ọ̀rẹ́ Àlàáfíà
a ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ń fọgbọ́n wàásù fún ọkùnrin kan nílé epo.