ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 26
ORIN 123 Máa Ṣègbọràn sí Ètò Ọlọ́run
Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
“Ó kọjá agbára wa láti lóye Olódùmarè.”—JÓÒBÙ 37:23.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa kọ́ bá a ṣe lè nírẹ̀lẹ̀ tá ò sì ní máa dara wa láàmú nípa àwọn nǹkan tá ò mọ̀ àti bá a ṣe lè gbájú mọ́ àwọn nǹkan tá a mọ̀, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.
1. Báwo ni Jèhófà ṣe dá wa, kí sì nìdí?
JÈHÓFÀ dá wa lọ́nà àgbàyanu. A lè kẹ́kọ̀ọ́, a lè lóye ohun tá a kọ́, a sì lè mọ bá a ṣe máa lo ohun tá a kọ́. Kí nìdí tí Jèhófà fi dá wa lọ́nà tá a fi lè ṣe àwọn nǹkan yìí? Ìdí ni pé ó fẹ́ ká ‘rí ìmọ̀ òun,’ ó sì fẹ́ ká máa ronú jinlẹ̀ bá a ṣe ń sin òun.—Òwe 2:1-5; Róòmù 12:1.
2. (a) Ṣé gbogbo nǹkan la mọ̀? (Jóòbù 37:23, 24) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.) (b) Àǹfààní wo la máa rí tá a bá gbà pé kì í ṣe gbogbo nǹkan la mọ̀?
2 Jèhófà dá wa lọ́nà tá a fi lè kẹ́kọ̀ọ́, síbẹ̀ àwọn nǹkan kan wà tá ò mọ̀. (Ka Jóòbù 37:23, 24.) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù. Jèhófà bi í láwọn ìbéèrè tó jẹ́ kó rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan lòun ò mọ̀. Àwọn ìbéèrè yẹn jẹ́ kó rí i pé ó yẹ kóun nírẹ̀lẹ̀, kóun sì yí èrò òun pa dà. (Jóòbù 42:3-6) Àwa náà máa rí ọ̀pọ̀ àǹfààní tá a bá nírẹ̀lẹ̀, tá a sì gbà pé kì í ṣe gbogbo nǹkan la mọ̀. Ìrẹ̀lẹ̀ máa mú ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tó yẹ ká mọ̀ ká lè ṣe ìpinnu tó tọ́.—Òwe 2:6.
Tá a bá gbà pé àwọn nǹkan kan wà tá ò mọ̀, ó máa ṣe wá láǹfààní bó ṣe ṣe Jóòbù náà láǹfààní (Wo ìpínrọ̀ 2)
3. Kí la máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tá ò mọ̀ àtàwọn ìṣòro tá a lè bá pàdé nínú ìjọsìn Ọlọ́run. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi dáa bá ò ṣe mọ àwọn nǹkan kan. Bá a ṣe ń jíròrò àwọn nǹkan yìí, ó máa túbọ̀ dá wa lójú pé ohun tó yẹ ká mọ̀ gan-an ni Jèhófà, “Ẹni tí ìmọ̀ rẹ̀ pé” ń sọ fún wa.—Jóòbù 37:16.
A Ò MỌ ÌGBÀ TÍ ÒPIN MÁA DÉ
4. Kí ni Mátíù 24:36 sọ pé a ò mọ̀?
4 Ka Mátíù 24:36. A ò mọ ìgbà tí ayé burúkú yìí máa dópin. Kódà nígbà tí Jésù wà láyé, òun náà ò mọ “ọjọ́ àti wákàtí”a tí òpin máa dé. Nígbà kan tó ń bá àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sọ pé Jèhófà tó jẹ́ Olùpàkókòmọ́ Tó Ga Jù Lọ máa ń ṣe nǹkan lásìkò tó bá sọ pé òun máa ṣe é torí “ìkáwọ́ rẹ̀” ni àsìkò wà, ó sì láṣẹ láti ṣe é. (Ìṣe 1:6, 7) Torí náà, Jèhófà ti mọ ọjọ́ àti wákàtí tí ayé burúkú yìí máa dópin, ṣùgbọ́n àwa ò mọ̀ ọ́n.
5. Nítorí a ò mọ ìgbà tí òpin máa dé, kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí wa?
5 Ohun tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé a ò mọ bó ṣe máa pẹ́ tó kí òpin tó dé. Torí náà, ó lè sú wa tàbí ká rẹ̀wẹ̀sì pàápàá tó bá ti pẹ́ tá a ti ń retí ọjọ́ Jèhófà. Ohun míì ni pé táwọn ará ilé wa àtàwọn ẹlòmíì bá ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, ó lè ṣòro fún wa láti fara dà á. (2 Pét. 3:3, 4) A lè rò pé tá a bá mọ ọjọ́ tí òpin máa dé, àá túbọ̀ ní sùúrù, á sì rọrùn fún wa láti fara dà á táwọn èèyàn bá ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́.
6. Kí nìdí tó fi dáa bá ò ṣe mọ ọjọ́ tí òpin máa dé?
6 Ká sòótọ́, bí Jèhófà ò ṣe jẹ́ ká mọ ọjọ́ tí òpin máa dé jẹ́ ká lè máa sìn ín tọkàntọkàn, ó ń jẹ́ ká fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, a sì gbẹ́kẹ̀ lé e. A ò sọ pé tí òpin ò bá tètè dé, a ò ní sin Jèhófà mọ́. Dípò ká máa ronú nípa ìgbà tí “ọjọ́ Jèhófà” máa dé, á dáa ká máa ronú nípa àwọn ohun rere tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá túbọ̀ máa sin Jèhófà tọkàntọkàn, àá sì máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti múnú ẹ̀ dùn.—2 Pét. 3:11, 12.
7. Kí làwọn nǹkan tá a mọ̀?
7 Á dáa ká gbájú mọ́ ohun tá a mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, a mọ̀ pé ọdún 1914 làwọn ọjọ́ ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀. Jèhófà jẹ́ ká mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa ọdún 1914, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà sì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn nǹkan táá máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà. Àwọn nǹkan tá a mọ̀ yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé “ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé.” (Sef. 1:14) Ohun míì tá a mọ̀ ni pé Jèhófà gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fún wa, ìyẹn ni iṣẹ́ wíwàásù “ìhìn rere Ìjọba” Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ èèyàn. (Mát. 24:14) À ń wàásù ìhìn rere yìí ní nǹkan bí igba ó lé ogójì (240) ilẹ̀ àti ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lọ. Torí náà, kò pọn dandan ká mọ “ọjọ́ àti wákàtí” tí ọjọ́ Jèhófà máa dé ká tó lè máa fìtara wàásù.
A Ò LÈ MỌ BÍ JÈHÓFÀ ṢE MÁA RÀN WÁ LỌ́WỌ́
8. Kí ni “iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́”? (Oníwàásù 11:5)
8 A ò lè mọ gbogbo “iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́.” (Ka Oníwàásù 11:5.) Ọ̀rọ̀ náà “iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́” ni ohun tí Jèhófà jẹ́ kó ṣẹlẹ̀ tàbí ohun tó fàyè gbà kí ìfẹ́ ẹ̀ lè ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, a ò lè mọ ìdí tí Jèhófà ṣe fàyè gba àwọn nǹkan kan, bákan náà a ò lè mọ bó ṣe máa ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 37:5) Bíbélì sọ pé a ò lè mọ gbogbo iṣẹ́ Ọlọ́run bá ò ṣe lè mọ bí ọmọ ṣe ń dàgbà nínú aláboyún, kódà àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì náà ò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bọ́mọ ṣe ń dàgbà nínú aláboyún.
9. Nítorí pé a ò mọ bí Jèhófà ṣe máa ràn wá lọ́wọ́, àwọn ìṣòro wo la lè bá pàdé nínú ìjọsìn Ọlọ́run?
9 Nígbà míì, ó lè má wù wá láti ṣe àwọn ìpinnu kan torí a ò mọ bí Jèhófà ṣe máa ràn wá lọ́wọ́. A lè máa bẹ̀rù láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, ó lè má rọrùn fún wa láti dín iṣẹ́ tá à ń ṣe kù ká lè ṣe púpọ̀ sí i tàbí kó má yá wa lára láti lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù sí i. A lè máa rò pé inú Ọlọ́run ò dùn sí wa tí ọwọ́ wa ò bá tẹ àwọn nǹkan tá a fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Bákan náà, a lè máa ṣiṣẹ́ kára láti wàásù, síbẹ̀ ká má lẹ́nì kankan tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A sì tún lè bá àwọn ìṣòro kan pàdé nígbà tá à ń ṣiṣẹ́ ètò Ọlọ́run.
10. Àwọn ànímọ́ pàtàkì wo la máa ní bá ò ṣe mọ bí Jèhófà ṣe máa ràn wá lọ́wọ́?
10 Bá ò ṣe mọ bí Jèhófà ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ máa jẹ́ ká láwọn ànímọ́ tó ṣe pàtàkì, bí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmọ̀wọ̀n ara ẹni. Ó jẹ́ ká gbà pé èrò àti ọ̀nà Jèhófà ga ju tiwa lọ. (Àìsá. 55:8, 9) Yàtọ̀ síyẹn, ó jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣàṣeyọrí. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé Jèhófà la máa ń yìn lógo tá a bá ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ ìwàásù tàbí nínú iṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run gbé fún wa. (Sm. 127:1; 1 Kọ́r. 3:7) Tí nǹkan ò bá tiẹ̀ rí bá a ṣe rò, ó yẹ ká rántí pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀. (Àìsá. 26:12) Tá a bá ṣáà ti ṣe ohun tó yẹ ká ṣe, ó yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa bójú tó wa. Bí Jèhófà ò tiẹ̀ bá wa sọ̀rọ̀ lọ́nà ìyanu bó ṣe ṣe fáwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, ọkàn wa balẹ̀ pé ó máa tọ́ wa sọ́nà.—Ìṣe 16:6-10.
11. Àwọn nǹkan wo la mọ̀ tó máa ràn wá lọ́wọ́?
11 A mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó máa ń ṣèdájọ́ òdodo, ó sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n. A tún mọ̀ pé ó mọyì gbogbo ohun tá à ń ṣe fún un àti bá a ṣe ń ran àwọn ará lọ́wọ́. A sì mọ̀ pé Jèhófà máa ń san àwọn olóòótọ́ lérè.—Héb. 11:6.
A Ò MỌ OHUN TÓ LÈ ṢẸLẸ̀ LỌ́LA
12. Bí Jémíìsì 4:13, 14 ṣe sọ, kí la ò mọ̀?
12 Ka Jémíìsì 4:13, 14. Òótọ́ kan ni pé a ò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí wa lọ́la. Nínú ayé burúkú yìí, “ìgbà àti èèṣì” lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni nínú wa. (Oníw. 9:11) Torí náà a ò lè mọ̀ bóyá ohun tá a fẹ́ ṣe máa yọrí sí rere tàbí a máa wà láàyè láti ṣe nǹkan náà parí.
13. Tá a bá ń ronú nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí wa, kí ló lè yọrí sí?
13 Tí ohun tá ò rò tẹ́lẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí wa, ó lè ṣòro fún wa láti fara dà á. Báwo nìyẹn ṣe lè ṣẹlẹ̀? Tá a bá ń ro ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí wa, ìyẹn lè má jẹ́ ká láyọ̀ mọ́. Tí àjálù tàbí nǹkan tá ò retí bá ṣẹlẹ̀, inú wa lè má dùn, ó sì lè jẹ́ kí nǹkan tojú sú wa. Bákan náà, tí nǹkan ò bá lọ bá a ṣe rò, ó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì.—Òwe 13:12.
14. Kí ló máa jẹ́ ká ní ayọ̀ tó máa wà títí lọ? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
14 Tá a bá fara da ìṣòro, àá fi hàn pé à ń sin Jèhófà nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, kì í ṣe nítorí ohun tá à ń rí gbà lọ́wọ́ ẹ̀. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó níṣòro, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà tá a bá níṣòro ni Jèhófà máa gbà wá sílẹ̀, kì í sì í ṣe pé Jèhófà ti kádàrá ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa. Ó mọ̀ pé a lè láyọ̀ tá ò bá tiẹ̀ mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́, tá a bá ń jẹ́ kó tọ́ wa sọ́nà, tá a sì ń ṣègbọràn, a máa láyọ̀. (Jer. 10:23) Tá a bá sì ń jẹ́ kó darí wa ká tó ṣèpinnu, àwa náà á lè sọ pé: “Tí Jèhófà bá fẹ́, a máa wà láàyè, a sì máa ṣe tibí tàbí tọ̀hún.”—Jém. 4:15.
Tá a bá jẹ́ kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà, tá a sì ń ṣègbọràn, ó máa dáàbò bò wá (Wo ìpínrọ̀ 14-15)b
15. Kí làwọn nǹkan tá a mọ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?
15 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, a mọ̀ pé Jèhófà ti ṣèlérí pé a máa ní ìyè àìnípẹ̀kun, bóyá ní ọ̀run tàbí ní ayé. A mọ̀ pé kò lè parọ́, kò sì sóhun tó lè ní kí gbogbo ìlérí ẹ̀ má ṣẹ. (Títù 1:2) Òun nìkan ló lè “sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀, tipẹ́tipẹ́ [ló] sì ti ń sọ àwọn ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀.” Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ nígbà àtijọ́ ló ṣẹ, ó sì dájú pé gbogbo ohun tó ṣèlérí pé òun máa ṣe lọ́jọ́ iwájú máa ṣẹ. (Àìsá. 46:10) A mọ̀ dájú pé kò sóhun tó lè ní kí Jèhófà má nífẹ̀ẹ́ wa mọ́. (Róòmù 8:35-39) Ó máa fún wa ní ọgbọ́n àti okun, á sì tù wá nínú ká lè fara da àwọn ìṣòro wa. Torí náà, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́, á sì bù kún wa.—Jer. 17:7, 8.
JÈHÓFÀ MỌ̀ WÁ JU BÁ A ṢE MỌ ARA WA LỌ
16. Kí ni Sáàmù 139:1-6 sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà mọ̀ wá ju bá a ṣe mọ ara wa lọ?
16 Ka Sáàmù 139:1-6. Torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, kò sóhun tí ò mọ̀ nípa wa títí kan ìrísí wa, ohun tá à ń rò àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa. Gbogbo ìgbà ló máa ń rí tiwa rò. Ó mọ ohun tá a sọ àtohun tá à ń rò àmọ́ tá ò tíì sọ, ó mọ ohun tá a ṣe àti ìdí tá a fi ṣe é. Ọba Dáfídì jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń bójú tó wa, kò sì pa wá tì. Ṣé kò yà wá lẹ́nu pé Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, Olódùmarè àti Ẹlẹ́dàá ń kíyè sí wa, ó sì ń bójú tó wa? Abájọ tí Dáfídì fi sọ pé: “Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ yà mí lẹ́nu gan-an. Ó jinlẹ̀ ju ohun tí mo lè lóye.”—Sm. 139:6, àlàyé ìsàlẹ̀.
17. Kí nìdí tó fi lè ṣòro fún wa láti gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa tàbí pé ó lè sún mọ́ wa?
17 Bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà, àṣà ìbílẹ̀ wa àtàwọn nǹkan tá a gbà gbọ́ ká tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lè mú kó ṣòro fún wa láti gbà pé Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ wa ni Jèhófà, ó sì rí tiwa rò. Ó lè máa ṣe wá bíi pé àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn pọ̀ gan-an débi pé Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ wa tàbí sún mọ́ wa. Kódà Dáfídì náà nírú èrò yìí láwọn ìgbà kan. (Sm. 38:18, 21) Ó sì lè jẹ́ pé ẹnì kan ń sapá láti ṣe àwọn àtúnṣe kan kó lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run, àmọ́ kó máa rò pé ‘Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run mọ bí nǹkan ṣe rí lára mi, kí ló dé tó fi fẹ́ kí n yí ìwà tó ti mọ́ mi lára pa dà?’
18. Tá a bá gbà pé Jèhófà mọ̀ wá ju bá a ṣe mọ ara wa lọ, báwo la ṣe máa jàǹfààní? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
18 Ó yẹ ká gbà pé Jèhófà mọ̀ wá ju bá a ṣe mọ ara wa lọ, ó sì ń rí ohun tó dáa nípa wa táwa ò rí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ń rí àwọn àṣìṣe wa, ó sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa àti ìdí tá a fi ń ṣe ohun tá à ń ṣe, ó ṣì nífẹ̀ẹ́ wa. (Róòmù 7:15) Tá a bá gbà pé Jèhófà mọ̀ pé a ṣì lè ṣe dáadáa, àá túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e, àá sì máa fayọ̀ sìn ín nìṣó.
Tí ohun tá ò rò tẹ́lẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí wa, Jèhófà máa jẹ́ ká lè fara dà á, tá a bá ń ronú nípa àwọn ohun rere tó máa ṣe fún wa nínú ayé tuntun (Wo ìpínrọ̀ 18-19)c
19. Kí làwọn nǹkan tá a mọ̀ nípa Jèhófà tó dá wa lójú?
19 A mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ ìfẹ́, òótọ́ pọ́ńbélé sì lọ̀rọ̀ yìí. (1 Jòh. 4:8) A mọ̀ pé àwọn ìlànà Jèhófà fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì fẹ́ káyé wa dùn. A mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ ká wà láàyè títí láé, ìdí nìyẹn tó fi pèsè ìràpadà. Ìràpadà ló jẹ́ ká lè máa sin Jèhófà bó ṣe fẹ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá. (Róòmù 7:24, 25) A tún mọ̀ pé “Ọlọ́run ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” (1 Jòh. 3:19, 20) Kò sóhun tí Jèhófà ò mọ̀ nípa wa, ó sì fọkàn tán wa pé a máa ṣe ìfẹ́ òun.
20. Kí ni ò ní jẹ́ ká dara wa láàmú nípa àwọn nǹkan tá ò mọ̀?
20 Gbogbo ohun tó yẹ ká mọ̀ ni Jèhófà ti sọ fún wa. Tá a bá gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, a ò ní máa dara wa láàmú nípa àwọn nǹkan tá ò mọ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì la máa gbájú mọ́. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, “Ẹni tí ìmọ̀ rẹ̀ pé.” (Jóòbù 36:4) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan kan wà tá ò mọ̀ báyìí, ó dá wa lójú pé títí láé làá máa kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá.—Oníw. 3:11.
ORIN 104 Ẹ̀bùn Ọlọ́run Ni Ẹ̀mí Mímọ́
b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Bàbá kan àti ọmọ ẹ̀ ń múra sílẹ̀ de àjálù, wọ́n ń kó àwọn nǹkan tí wọ́n nílò sínú báàgì pàjáwìrì wọn.
c ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan tó níṣòro ń ronú nípa àwọn ohun rere tó máa gbádùn nínú ayé tuntun.