ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 25
ORIN 96 Ìṣúra Ni Ìwé Ọlọ́run
Ohun Tá A Kọ́ Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Tí Jékọ́bù Sọ Nígbà Tó Fẹ́ Kú—Apá Kejì
“Ó súre fún kálukú bó ṣe tọ́ sí i.”—JẸ́N. 49:28.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ fáwọn ọmọkùnrin ẹ̀ mẹ́jọ tó kù nígbà tó fẹ́ kú.
1. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
ÀWỌN ọmọkùnrin Jékọ́bù yí i ká, wọ́n ń fara balẹ̀ gbọ́ bí bàbá wọn ṣe ń súre fún wọn lọ́kọ̀ọ̀kan. Bá a ṣe jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, àwọn ọ̀rọ̀ tí Jékọ́bù sọ fún Rúbẹ́nì, Síméónì, Léfì àti Júdà yà wọ́n lẹ́nu gan-an. Torí náà, wọ́n á fẹ́ mọ ohun tí bàbá wọn máa sọ fáwọn mẹ́jọ tó kù. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun tá a lè kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jékọ́bù sọ fún Sébúlúnì, Ísákà, Dánì, Gádì, Áṣérì, Náfútálì, Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì.a
SÉBÚLÚNÌ
2. Kí ni Jékọ́bù sọ fún Sébúlúnì, báwo ló sì ṣe ṣẹ? (Jẹ́nẹ́sísì 49:13) (Tún wo àpótí.)
2 Ka Jẹ́nẹ́sísì 49:13. Jékọ́bù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn àtọmọdọ́mọ Sébúlúnì máa gbé etíkun ní apá àríwá Ilẹ̀ Ìlérí. Igba (200) ọdún ti kọjá kí àsọtẹ́lẹ̀ náà tó ṣẹ, ìgbà yẹn làwọn ọmọ Sébúlúnì gba ilẹ̀ wọn. Ilẹ̀ náà wà láàárín Òkun Gálílì àti Òkun Mẹditaréníà. Mósè sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ìwọ Sébúlúnì, máa yọ̀ bí o ṣe ń jáde lọ.” (Diu. 33:18) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí Mósè ń sọ ni bó ṣe máa rọrùn fún Sébúlúnì láti máa ṣòwò torí pé òkun méjì ló yí i ká. Èyí ó wù kó jẹ́, ó yẹ káwọn àtọmọdọ́mọ Sébúlúnì máa yọ̀.
3. Kí ló máa jẹ́ kóhun tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn?
3 Ohun tá a kọ́. Ibi yòówù ká máa gbé tàbí ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí wa, ó yẹ ká máa láyọ̀ nígbà gbogbo. Tá a bá fẹ́ máa láyọ̀, ó yẹ ká jẹ́ káwọn nǹkan tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn. (Sm. 16:6; 24:5) Nígbà míì, a sábà máa ń ronú nípa àwọn nǹkan tá ò ní débi tá ò fi ní mọyì àwọn nǹkan tá a ní. Torí náà, ó yẹ kó o máa ronú nípa àwọn nǹkan tó dáa tí Jèhófà ń ṣe fún ẹ, kó o sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀.—Gál. 6:4.
ÍSÁKÀ
4. Kí ni Jékọ́bù sọ fún Ísákà, báwo ló sì ṣe ṣẹ? (Jẹ́nẹ́sísì 49:14, 15) (Tún wo àpótí.)
4 Ka Jẹ́nẹ́sísì 49:14, 15. Jékọ́bù gbóríyìn fún Ísákà torí ó máa ń ṣiṣẹ́ kára, ó sì fi wé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí eegun ẹ̀ le, ìyẹn ẹranko tó máa ń gbé ẹrù tó wúwo. Jékọ́bù tún sọ pé Ísákà máa ní ilẹ̀ tó dáa. Ohun tí Jékọ́bù sọ ṣẹ torí àwọn àtọmọdọ́mọ Ísákà gba ilẹ̀ tó lọ́ràá lẹ́gbẹ̀ẹ́ Odò Jọ́dánì. (Jóṣ. 19:22) Ó dájú pé wọ́n ṣiṣẹ́ kára gan-an láti dáko sórí ilẹ̀ wọn, àmọ́ wọ́n tún ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. (1 Ọba 4:7, 17) Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀yà Ísákà wà lára àwọn ẹ̀yà tó lọ jagun nígbà tí Bárákì onídàájọ́ àti Dèbórà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n lọ bá àwọn ọ̀tá jà, wọ́n sì ṣe tán láti ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù lọ́wọ́ nígbàkigbà.—Oníd. 5:15.
5. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣiṣẹ́ kára?
5 Ohun tá a kọ́. Jèhófà mọyì iṣẹ́ àṣekára tá à ń ṣe nínú ìjọsìn ẹ̀ bó ṣe mọyì iṣẹ́ àṣekára tí ẹ̀yà Ísákà ṣe. (Oníw. 2:24) Ẹ kíyè sí iṣẹ́ àṣekára táwọn alàgbà tó ń bójú tó ìjọ ń ṣe. (1 Tím. 3:1) Àwọn arákùnrin yìí kì í jagun, àmọ́ wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti dáàbò bo àwọn ará ìjọ kí àjọṣe wọn àti Jèhófà má bàa bà jẹ́. (1 Kọ́r. 5:1, 5; Júùdù 17-23) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún máa ń ṣiṣẹ́ kára láti múra àsọyé kí wọ́n sì sọ ọ́ lọ́nà tó máa fún àwọn ará ìjọ lókun.—1 Tím. 5:17.
DÁNÌ
6. Iṣẹ́ wo ni ẹ̀yà Dánì ṣe? (Jẹ́nẹ́sísì 49:17, 18) (Tún wo àpótí.)
6 Ka Jẹ́nẹ́sísì 49:17, 18. Jékọ́bù fi Dánì wé ejò kan tó ń bá àwọn ẹranko tó jù ú lọ jà, irú bí ẹṣin tí wọ́n fi ń jagun. Dánì nígboyà gan-an, ó sì múra tán láti gbéjà ko àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì. Nígbà tí wọ́n ń rìn lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí, ẹ̀yà Dánì dáàbò bo orílẹ̀-èdè náà, “àwọn ni wọ́n wà lẹ́yìn tí wọ́n ń ṣọ́” gbogbo ibùdó náà. (Nọ́ń. 10:25) Iṣẹ́ pàtàkì ni ẹ̀yà Dánì ń ṣe bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù mọ̀.
7. Ojú wo ló yẹ ká fi wo iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún wa nínú ètò Ọlọ́run?
7 Ohun tá a kọ́. Ṣé o ti ṣe iṣẹ́ ìjọ rí, tó sì ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn èèyàn ò rí ohun tó ò ń ṣe? Ó lè jẹ́ pé o ṣe iṣẹ́ ìmọ́tótó Ilé Ìpàdé tàbí kó o ṣe àwọn àtúnṣe kan níbẹ̀. Ó sì lè jẹ́ pé o yọ̀ǹda ara ẹ láti ṣiṣẹ́ ní àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ agbègbè tàbí kó o ṣe àwọn iṣẹ́ míì. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a gbóríyìn fún ẹ gan-an! Máa rántí pé Jèhófà rí gbogbo ohun tó ò ń ṣe, ó sì mọyì ẹ̀. Jèhófà mọrírì iṣẹ́ ìsìn ẹ, tó bá jẹ́ torí pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ lo ṣe ń ṣe é, tí kì í ṣe torí káwọn èèyàn lè máa yìn ẹ́.—Mát. 6:1-4.
GÁDÌ
8. Kí ló mú kó rọrùn fáwọn ọ̀tá láti gbéjà ko ẹ̀yà Gádì ní Ilẹ̀ Ìlérí? (Jẹ́nẹ́sísì 49:19) (Tún wo àpótí.)
8 Ka Jẹ́nẹ́sísì 49:19. Jékọ́bù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn jàǹdùkú máa ja Gádì lólè. Lẹ́yìn igba (200) ọdún, ẹ̀yà Gádì gba ilẹ̀ kan tó wà ní ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì, ilẹ̀ náà wà ní ààlà àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ọ̀tá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ibi tí ilẹ̀ náà wà mú kó rọrùn fáwọn ọ̀tá láti gbéjà kò wọ́n nígbàkigbà. Síbẹ̀, ibi táwọn ẹ̀yà Gádì fẹ́ máa gbé nìyẹn torí pé wọ́n á máa rí koríko tó pọ̀ fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn. (Nọ́ń. 32:1, 5) Ó hàn gbangba pé àwọn ẹ̀yà Gádì nígboyà gan-an. Àmọ́ ju gbogbo ẹ̀ lọ, wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa ran àwọn lọ́wọ́, kò sì ní jẹ́ káwọn ọ̀tá gba ilẹ̀ tó fún wọn. Ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n fi jẹ́ káwọn ọmọ ogun wọn lọ ran àwọn ẹ̀yà tó kù lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ilẹ̀ tiwọn náà gbà ní apá ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì ní Ilẹ̀ Ìlérí. (Nọ́ń. 32:16-19) Wọ́n gbà pé Jèhófà máa dáàbò bo ìyàwó àtàwọn ọmọ wọn nígbà tí wọn ò sí nílé. Torí pé wọ́n nígboyà, wọ́n sì ran àwọn míì lọ́wọ́ bí ò tiẹ̀ rọrùn, Jèhófà dáàbò bò wọ́n.—Jóṣ. 22:1-4.
9. Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa bójú tó wa, irú àwọn ìpinnu wo la máa ṣe?
9 Ohun tá a kọ́. Tá a bá fẹ́ máa sin Jèhófà nìṣó nígbà ìṣòro, a gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá. (Sm. 37:3) Ọ̀pọ̀ lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà là ń yááfì nǹkan, tá a sì ń fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé ètò Ọlọ́run, àwọn míì ń sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, àwọn míì sì ń bójú tó àwọn iṣẹ́ míì nínú ètò Ọlọ́run. Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí ó dá wọn lójú pé Jèhófà máa bójú tó wọn.—Sm. 23:1.
ÁṢÉRÌ
10. Kí ni ẹ̀yà Áṣérì ò ṣe? (Jẹ́nẹ́sísì 49:20) (Tún wo àpótí.)
10 Ka Jẹ́nẹ́sísì 49:20. Jékọ́bù sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹ̀yà Áṣérì máa lọ́rọ̀ gan-an, ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyẹn torí pé ilẹ̀ tí wọ́n pín fún wọn wà lára àwọn ilẹ̀ tó lọ́ràá jù ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. (Diu. 33:24) Yàtọ̀ síyẹn, ààlà ilẹ̀ náà wà ní Òkun Mẹditaréníà títí kan etíkun Sídónì táwọn ará Foníṣíà ti ń ṣòwò. Àmọ́ ohun kan wà tí ẹ̀yà Áṣérì ò ṣe, wọn ò lé àwọn ọmọ Kénáánì kúrò ní ilẹ̀ náà. (Oníd. 1:31, 32) Yàtọ̀ síyẹn, wọn ò tẹ̀ lé Bárákì nígbà tó ń wá àwọn tó máa lọ bá àwọn ọmọ Kénáánì jà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọrọ̀ tí ẹ̀yà Áṣérì ní àti àkóbá táwọn ọmọ Kénáánì ṣe fún wọn ni ò jẹ́ kí wọ́n fi bẹ́ẹ̀ nítara nínú ìjọsìn Ọlọ́run mọ́. Torí náà, ẹ̀yà náà ò sí níbẹ̀ nígbà tí Jèhófà jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun lọ́nà ìyanu “létí omi Mẹ́gídò.” (Oníd. 5:19-21) Ó dájú pé ojú máa ti ẹ̀yà Áṣérì nígbà tí wọ́n ń gbọ́ orin ìṣẹ́gun tí Bárákì àti Dèbórà ń kọ, apá kan orin náà sọ pé: “Áṣérì jókòó gẹlẹtẹ sí etíkun.”—Oníd. 5:17.
11. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká lo gbogbo àkókò àti okun wa fáwọn nǹkan tara?
11 Ohun tá a kọ́. Ó wù wá ká lo gbogbo okun àti agbára wa fún Jèhófà. Tá a bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní máa lépa ohun ìní àti ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ. (Òwe 18:11) Lóòótọ́ a nílò owó, àmọ́ a ò ní jẹ́ kí owó ṣe pàtàkì ju ìjọsìn Ọlọ́run lọ. (Oníw. 7:12; Héb. 13:5) A ò ní máa fi gbogbo okun àti àkókò wa wá àwọn nǹkan tí ò ṣe pàtàkì tó sì máa dí ìjọsìn Ọlọ́run lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká lo gbogbo okun wa fún Jèhófà torí a mọ̀ pé ìgbésí ayé aláyọ̀ la máa gbé lọ́jọ́ iwájú.—Sm. 4:8.
NÁFÚTÁLÌ
12. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nípa Náfútálì ṣe ṣẹ? (Jẹ́nẹ́sísì 49:21) (Tún wo àpótí.)
12 Ka Jẹ́nẹ́sísì 49:21. Nígbà tí Jékọ́bù sọ tẹ́lẹ̀ pé Náfútálì máa sọ “ọ̀rọ̀ tó dùn,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí Jésù ṣe máa sọ̀rọ̀ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ ló ń sọ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn èèyàn máa ń gbádùn ẹ̀kọ́ Jésù gan-an, ó sì lo ọ̀pọ̀ àkókò ní Kápánáúmù tó wà lágbègbè Náfútálì, kódà ó sọ ọ́ di “ìlú rẹ̀.” (Mát. 4:13; 9:1; Jòh. 7:46) Nígbà tí Àìsáyà ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jésù, ó sọ pé àwọn èèyàn Sébúlúnì àti Náfútálì máa rí “ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò.” (Àìsá. 9:1, 2) Jésù ni “ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ tó ń fún onírúurú èèyàn ní ìmọ́lẹ̀” torí ó ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.—Jòh. 1:9.
13. Kí ló yẹ ká ṣe kọ́rọ̀ ẹnu wa lè máa múnú Jèhófà dùn?
13 Ohun tá a kọ́. Jèhófà máa ń kíyè sí ohun tá a sọ fáwọn èèyàn àti bá a ṣe sọ ọ́. Báwo la ṣe lè máa sọ “ọ̀rọ̀ tó dùn” kínú Jèhófà sì dùn sí wa? Ó yẹ ká máa sòótọ́ nígbà gbogbo. (Sm. 15:1, 2) Ká máa sọ̀rọ̀ tó ń gbé àwọn èèyàn ró, ìyẹn ni pé ká máa tètè gbóríyìn fún wọn, àmọ́ ká má tètè ṣàríwísí wọn. (Éfé. 4:29) A tún lè pinnu pé àá máa wá bá a ṣe lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ká lè wàásù fún wọn.
JÓSẸ́FÙ
14. Ṣàlàyé bí àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nípa Jósẹ́fù ṣe ṣẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 49:22, 26) (Tún wo àpótí.)
14 Ka Jẹ́nẹ́sísì 49:22, 26. Jékọ́bù fẹ́ràn Jósẹ́fù gan-an torí ọmọ àmúyangàn ni, kódà Ọlọ́run yà á “sọ́tọ̀ láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀.” Jékọ́bù pè é ní “èéhù igi eléso.” Jékọ́bù fúnra ẹ̀ ni igi náà, Jósẹ́fù sì ni èéhù igi náà. Jósẹ́fù ni àkọ́bí Réṣẹ́lì, ìyẹn ìyàwó tí Jékọ́bù fẹ́ràn gan-an. Jékọ́bù sọ pé Jósẹ́fù máa gba ìpín méjì, ìyẹn ìpín tí Rúbẹ́nì àkọ́bí Líà pàdánù. (Jẹ́n. 48:5, 6; 1 Kíró. 5:1, 2) Àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ torí pé àwọn ọmọ Jósẹ́fù, ìyẹn Éfúrémù àti Mánásè gba ilẹ̀ kọ̀ọ̀kan tó wá jẹ́ kí ìdílé Jósẹ́fù gba ìpín méjì.—Jẹ́n. 49:25; Jóṣ. 14:4.
15. Kí ni Jósẹ́fù ṣe nígbà tí wọ́n hùwà ìkà sí i?
15 Jékọ́bù tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn tafàtafà tó ‘ta Jósẹ́fù lọ́fà, tí wọ́n sì dì í sínú.’ (Jẹ́n. 49:23) Àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ làwọn tafàtafà yẹn torí wọ́n hùwà ìkà sí i, àwọn ló sì fa ọ̀pọ̀ lára ìyà tó jẹ ẹ́. Síbẹ̀, Jósẹ́fù ò bínú sáwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ tàbí kó bínú sí Jèhófà. Jékọ́bù sọ pé: “Ọfà [Jósẹ́fù] dúró sí àyè rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ lágbára, ó sì já fáfá.” (Jẹ́n. 49:24) Jósẹ́fù gbára lé Jèhófà ní gbogbo àsìkò tó níṣòro yẹn, ó tún dárí ji àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀, kódà ó finúure hàn sí wọn. (Jẹ́n. 47:11, 12) Jósẹ́fù kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i, ìyẹn sì mú kó túbọ̀ níwà tó dáa. (Sm. 105:17-19) Torí náà, Jèhófà mú kó gbé àwọn nǹkan ńlá ṣe.
16. Báwo la ṣe lè fara wé Jósẹ́fù tá a bá níṣòro?
16 Ohun tá a kọ́. Ẹ má ṣe jẹ́ káwọn ìṣòro tá a ní mú ká fi Jèhófà àtàwọn ará sílẹ̀. Máa rántí pé Jèhófà lè gbà káwọn nǹkan kan dán ìgbàgbọ́ wa wò ká lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ẹ̀. (Héb. 12:7, àlàyé ìsàlẹ̀) Ohun tá a kọ́ yẹn máa jẹ́ ká túbọ̀ láwọn ìwà Kristẹni bíi ká máa fàánú hàn sáwọn èèyàn, ká sì máa dárí jì wọ́n. (Héb. 12:11) Bí Jèhófà ṣe san èrè fún Jósẹ́fù, ó máa san èrè fáwa náà tá a bá fara dà á.
BẸ́ŃJÁMÍNÌ
17. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nípa Bẹ́ńjámínì ṣe ṣẹ? (Jẹ́nẹ́sísì 49:27) (Tún wo àpótí.)
17 Ka Jẹ́nẹ́sísì 49:27. Jékọ́bù sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì á máa jà bí ìkookò. (Oníd. 20:15, 16; 1 Kíró. 12:2) Ní ìbẹ̀rẹ̀, ìyẹn “ní àárọ̀” ìjọba Ísírẹ́lì, Sọ́ọ̀lù tó wá láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ló kọ́kọ́ jọba. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì gbéjà ko àwọn Filísínì. (1 Sám. 9:15-17, 21) “Ní ìrọ̀lẹ́” ìjọba Ísírẹ́lì, Ayaba Ẹ́sítà àti Módékáì tó jẹ́ igbá kejì ọba Páṣíà gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ nígbà táwọn kan fẹ́ pa wọ́n run nígbà ìjọba Páṣíà, ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì làwọn méjèèjì sì ti wá.—Ẹ́sít. 2:5-7; 8:3; 10:3.
18. Báwo la ṣe lè fara wé ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì tó fara mọ́ ètò tí Jèhófà ṣe?
18 Ohun tá a kọ́. Ó dájú pé inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì dùn gan-an nígbà tí ọ̀kan lára wọn di ọba, tí àsọtẹ́lẹ̀ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ. Àmọ́ nígbà tí Jèhófà gbé ìjọba náà fún Dáfídì tó wá látinú ẹ̀yà Júdà, níkẹyìn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì fara mọ́ ọn. (2 Sám. 3:17-19) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà táwọn ẹ̀yà tó kù ta ko ẹ̀yà Júdà, ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ti Júdà lẹ́yìn àti ọba tí Jèhófà yàn. (1 Ọba 11:31, 32; 12:19, 21) Ẹ jẹ́ káwa náà pinnu pé a máa fara mọ́ àwọn tí Jèhófà yàn pé kó máa bójú tó wa lónìí.—1 Tẹs. 5:12.
19. Báwo la ṣe lè jàǹfààní nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nígbà tó fẹ́ kú?
19 Àwa náà lè jàǹfààní nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nígbà tó fẹ́ kú. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ, á jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà sọ nínú Bíbélì máa ṣẹ. Bákan náà, tá a bá ń wo bí Jèhófà ṣe bù kún àwọn ọmọ Jékọ́bù, á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè múnú Jèhófà dùn.
ORIN 128 Bí A Ṣe Lè Fara Dà Á Dópin
a Jékọ́bù súre fún Rúbẹ́nì, Síméónì, Léfì àti Júdà látorí ẹni tó dàgbà jù dórí ẹni tó kéré jù, lẹ́yìn náà Jékọ́bù súre fáwọn ọmọ tó kù láìwo bí ọjọ́ orí wọn ṣe tò tẹ̀ léra.