Ẹ̀KỌ́ 13
Jékọ́bù àti Ísọ̀ Parí Ìjà Wọn
Jèhófà ṣèlérí fún Jékọ́bù pé òun máa dáàbò bò ó bóun ṣe dáàbò bo Ábúráhámù àti Ísákì. Ìlú Háránì ni Jékọ́bù ń gbé, ó fẹ́ ìyàwó níbẹ̀, ó ní ọmọ tó pọ̀, ó ní àwọn ìránṣẹ́, ó sì ní nǹkan tó pọ̀ gan-an.
Nígbà tó yá, Jèhófà sọ fún Jékọ́bù pé: ‘Pa dà sí ìlú rẹ.’ Torí náà, Jékọ́bù àti ìdílé ẹ̀ gbéra, wọ́n sì rìnrìn àjò pa dà sílé. Ojú ọ̀nà ni wọ́n wà táwọn èèyàn kan ti wá sọ fún Jékọ́bù pé: ‘Ísọ̀ ìkejì ẹ ń bọ̀ wá pàdé ẹ, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin ló sì wà pẹ̀lú ẹ̀!’ Ẹ̀rù ba Jékọ́bù, torí ó gbà pé ńṣe ni Ísọ̀ fẹ́ wá bá òun àti ìdílé òun jà. Ó wá gbàdúrà sí Jèhófà pé: ‘Jọ̀ọ́ Jèhófà, gbà mí lọ́wọ́ ìkejì mi.’ Lọ́jọ́ kejì, Jékọ́bù fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Ísọ̀. Àwọn nǹkan tó fi ránṣẹ́ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgùntàn, ewúrẹ́, màlúù, ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
Nígbà tí Jékọ́bù dá wà lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ó rí áńgẹ́lì kan. Òun àti áńgẹ́lì yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í jà títí di àárọ̀ ọjọ́ kejì. Jékọ́bù ṣèṣe, síbẹ̀ kò fi áńgẹ́lì náà sílẹ̀. Áńgẹ́lì yẹn wá sọ pé: ‘Fi mi sílẹ̀, jẹ́ kí n máa lọ.’ Àmọ́ Jékọ́bù sọ pé: ‘Mi ò ní fi ẹ́ sílẹ̀, àyàfi tó o bá súre fún mi.’
Nígbà tó yá, áńgẹ́lì náà súre fún Jékọ́bù. Ó wá dá Jékọ́bù lójú pé Jèhófà ò ní jẹ́ kí Ísọ̀ bá òun jà.
Nígbà tílẹ̀ mọ́, Jékọ́bù rí Ísọ̀ àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin tí wọ́n ń bọ̀ ní iwájú. Jékọ́bù fi ìdílé ẹ̀ sílẹ̀ sẹ́yìn, ó lọ bá Ísọ̀, ó sì tẹrí ba fún un nígbà méje. Ísọ̀ náà sáré lọ bá Jékọ́bù, ó sì dì mọ́ ọn. Àwọn méjèèjì bú sẹ́kún, wọ́n sì parí ìjà wọn. Ǹjẹ́ o rò pé inú Jèhófà dùn sí ọ̀nà tí Jékọ́bù gbà yanjú ọ̀rọ̀ yẹn?
Lẹ́yìn náà, Ísọ̀ pa dà sílé ẹ̀, Jékọ́bù náà sì pa dà sílé tiẹ̀. Ọmọkùnrin méjìlá (12) ni Jékọ́bù ní. Orúkọ wọn ni Rúbẹ́nì, Síméónì, Léfì, Júdà, Dánì, Náfútálì, Gádì, Áṣérì, Ísákà, Sébúlúnì, Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì. Jèhófà lo ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin yẹn láti gba àwọn ìbátan ẹ̀ là. Ọmọkùnrin náà ni Jósẹ́fù. Ṣé o mọ bí Jèhófà ṣe lò ó? Ẹ jẹ́ ká wò ó.
“Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí yín, kí ẹ lè fi hàn pé ọmọ Baba yín tó wà ní ọ̀run lẹ jẹ́.”—Mátíù 5:44, 45