ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 10/1 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìbejì Tí Wọn Ò Jọra
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Jékọ́bù Rí Ogún Gbà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Jékọ́bù àti Ísọ̀ Parí Ìjà Wọn
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Rèbékà—Akíkanjú Obìnrin Tó Bẹ̀rù Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 10/1 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ṣé ó burú bí Jékọ́bù ṣe pe ara rẹ̀ ní Ísọ̀, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì 27:18, 19?

Ó ṣeé ṣe kó o mọ ìtàn yìí. Ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Ísákì darúgbó, ó sọ fún Ísọ̀ pé kó lọ sóko ọdẹ kó lọ pa ẹran ìgbẹ́ fóun, ó ní: “Kí n sì jẹ ẹ́, kí ọkàn mi lè súre fún ọ, kí n tó kú.” Nígbà tí Rèbékà gbọ́ ohun tí ọkọ rẹ̀ wí yìí, ó se oúnjẹ aládùn kan, ó sì sọ fún Jékọ́bù pé: “Kí o gbé [oúnjẹ náà] lọ sọ́dọ̀ baba rẹ, kí ó sì jẹ ẹ́, kí ó lè súre fún ọ, ṣáájú ikú rẹ̀.” Lẹ́yìn náà ni Jékọ́bù wọ ẹ̀wù Ísọ̀, ó sì fi awọ ọmọ ewúrẹ́ bo ọrùn àti ọwọ́ rẹ̀, ó wá gbé oúnjẹ aládùn náà lọ fún bàbá rẹ̀. Nígbà tí Ísákì bi í pé, “Ta ni ọ́, ọmọkùnrin mi?” Jékọ́bù dáhùn pé: “Èmi ni Ísọ̀ àkọ́bí rẹ.” Ísákì gbà á gbọ́, ó sì súre fún un.—Jẹ́nẹ́sísì 27:1-29.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó mú kí Rèbékà àti Jékọ́bù ṣe ohun tí wọ́n ṣe yìí, síbẹ̀ ó jẹ́ ká rí i pé ọ̀rọ̀ yìí ṣàdédé wáyé ni láìjẹ́ pé wọ́n ti jọ rò ó tẹ́lẹ̀. Ó yẹ ká mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò sọ pé ohun tí Rèbékà àti Jékọ́bù ṣe yìí dára tàbí ó burú. Nítorí náà, èèyàn ò lè tìtorí ohun tí wọ́n ṣe yìí sọ pé irọ́ pípa àti ẹ̀tàn dára. Àmọ́ Bíbélì ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà yé wa yékéyéké.

Ohun àkọ́kọ́ ni pé, ìtàn yẹn jẹ́ ká rí i kedere pé Jékọ́bù lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ìre lẹ́nu bàbá rẹ̀, àmọ́ Ísọ̀ kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i. Ṣáájú ìgbà yẹn, Jékọ́bù ti fi ẹ̀tọ́ ra ipò àkọ́bí lọ́wọ́ ẹní tí wọ́n jọ jẹ́ ìbejì, ìyẹn Ísọ̀ tí kò mọrírì ẹ̀tọ́ tó ní gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí tó sì tà á nítorí oúnjẹ nígbà tébi ń pa á. Ísọ̀ “tẹ́ńbẹ́lú ogún ìbí náà.” (Jẹ́nẹ́sísì 25:29-34) Nítorí náà, nígbà tí Jékọ́bù lọ bá bàbá rẹ̀, ńṣe ló fẹ́ gba ìre tó tọ́ sí i.

Ohun kejì ni pé, nígbà tí Ísákì mọ̀ pé òun ti súre fún Jékọ́bù, kò wá ọ̀nà láti yí ìre tó ti sú náà padà. Ó ṣeé ṣe kó rántí ohun tí Jèhófà sọ fún Rèbékà kó tó bí àwọn ìbejì náà. Jèhófà sọ pé: “Ẹ̀gbọ́n ni yóò sì sin àbúrò.” (Jẹ́nẹ́sísì 25:23) Ohun mìíràn tó yẹ ká tún kíyè sí ni pé nígbà tí Jékọ́bù fẹ́ kúrò ní Háránì, Ísákì tún fi kún ìre tó ti sú fún un tẹ́lẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 28:1-4.

Lékè gbogbo rẹ̀, ó yẹ ká rántí pé gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ yìí kò ṣókùnkùn sí Jèhófà ó sì mọ̀ nípa rẹ̀. Ìre tí Ísákì sú fún Jékọ́bù ní í ṣe pẹ̀lú ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù. (Jẹ́nẹ́sísì 12:2, 3) Bí Ọlọ́run ò bá fẹ́ kí ìre náà jẹ́ ti Jékọ́bù, ì bá ti yí ọ̀rọ̀ náà padà lọ́nà kan tàbí òmíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà túbọ̀ mú ọ̀rọ̀ náà dá Jékọ́bù lójú, ó sọ fún un pé: “Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni gbogbo àwọn ìdílé ilẹ̀ yóò bù kún ara wọn dájúdájú.”—Jẹ́nẹ́sísì 28:10-15.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́