Ẹ̀KỌ́ 12
Jékọ́bù Rí Ogún Gbà
Nígbà tí Ísákì pé ẹni ogójì (40) ọdún, ó fẹ́ Rèbékà. Ísákì nífẹ̀ẹ́ Rèbékà ìyàwó ẹ̀ gan-an. Nígbà tó yá, wọ́n bí ìbejì, ọkùnrin sì làwọn méjèèjì.
Orúkọ èyí àkọ́kọ́ ni Ísọ̀, orúkọ èkejì sì ni Jékọ́bù. Ísọ̀ fẹ́ràn kó máa ṣeré jáde, ó sì tún máa ń pa ẹran gan-an. Àmọ́ Jékọ́bù fẹ́ràn kó máa wà nílé.
Láyé àtijọ́, tí bàbá kan bá kú, àkọ́bí ẹ̀ ọkùnrin ló máa ń gba ohun tó pọ̀ jù lára ohun tí bàbá náà ní. Àwọn nǹkan tí bàbá náà fi sílẹ̀ lẹ́yìn tó kú là ń pè ní ogún. Àwọn ìlérí tí Jèhófà bá Ábúráhámù ṣe wà lára ogún ìdílé Ísákì. Ísọ̀ ò ka àwọn ìlérí yẹn sí pàtàkì, àmọ́ Jékọ́bù mọyì àwọn ìlérí yẹn gan-an.
Lọ́jọ́ kan tí Ísọ̀ dé láti ibi tó ti lọ pa ẹran, ó ti rẹ̀ ẹ́ gan-an. Nígbà tó wọlé, ó gbóòórùn oúnjẹ tí Jékọ́bù ń sè, ó wá sọ fún un pé: ‘Ebi ń pa mí gan-an! Fún mi ní díẹ̀ lára oúnjẹ tó ò ń sè!’ Jékọ́bù dáhùn pé: ‘Màá fún ẹ, àmọ́ kọ́kọ́ ṣèlérí fún mi pé èmi ni màá gba ogún tó yẹ kó o gbà.’ Ísọ̀ wá dáhùn pé: ‘Kí ló kàn mí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ogún! Wò ó, ó ti di tìẹ. Ṣáà fún mi lóúnjẹ.’ Ṣé o rò pé ohun tí Ísọ̀ ṣe yẹn bọ́gbọ́n mu? Kò bọ́gbọ́n mu rárá. Ísọ̀ sọ ohun pàtàkì nù torí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan péré.
Nígbà tí Ísákì darúgbó, ó rí i pé ó yẹ kóun bù kún àkọ́bí òun. Àmọ́ Rèbékà ìyá wọn ran Jékọ́bù tó jẹ́ àbúrò lọ́wọ́, Jékọ́bù ló sì rí ìbùkún náà gbà. Nígbà tí Ísọ̀ mọ̀ pé Jékọ́bù ti gba ìbùkún tó yẹ kóun gbà, inú bí i gan-an, ó sì pinnu pé òun máa pa ìkejì òun. Ísákì àti Rèbékà ò fẹ́ kí Jékọ́bù kú, torí náà wọ́n sọ fún un pé: ‘Ó yá, wá lọ máa gbé lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n màmá ẹ títí dìgbà tí inú Ísọ̀ á fi rọ̀.’ Jékọ́bù ṣe ohun táwọn òbí ẹ̀ sọ fún un, ó sì sá kúrò nílé.
“Àǹfààní wo ni èèyàn máa rí tó bá jèrè gbogbo ayé, tó sì wá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀? Ká sòótọ́, kí ni èèyàn máa fi dípò ẹ̀mí rẹ̀?”—Máàkù 8:36, 37