ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 24
ORIN 98 Ọlọ́run Ló Mí sí Ìwé Mímọ́
Ohun Tá A Kọ́ Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Tí Jékọ́bù Sọ Nígbà Tó Fẹ́ Kú—Apá Kìíní
“Ẹ kó ara yín jọ, kí n lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí yín lọ́jọ́ iwájú.”—JẸ́N. 49:1.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀ nígbà tó fẹ́ kú. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa Rúbẹ́nì, Síméónì, Léfì àti Júdà.
1-2. Kí ni Jékọ́bù ṣe nígbà tó fẹ́ kú, kí sì nìdí? (Tún wo àwòrán.)
NǸKAN bí ọdún mẹ́tàdínlógún (17) ti kọjá lẹ́yìn tí Jékọ́bù àti ìdílé ẹ̀ fi ilẹ̀ Kénáánì sílẹ̀, tí wọ́n sì rìnrìn àjò lọ sí Íjíbítì. (Jẹ́n. 47:28) Nígbà tí Jékọ́bù dé Íjíbítì, inú ẹ̀ dùn pé ó pa dà rí Jósẹ́fù ọmọ ẹ̀, inú ẹ̀ sì tún dùn pé gbogbo wọn pa dà wà pa pọ̀. Àmọ́ nígbà tó yá, Jékọ́bù mọ̀ pé òun ò ní pẹ́ kú. Torí náà, ó pe àwọn ọmọ ẹ̀ jọ kó lè bá wọn sọ̀rọ̀ pàtàkì.—Jẹ́n. 49:28.
2 Láyé ìgbà yẹn, tí olórí ìdílé kan bá ti mọ̀ pé òun ò ní pẹ́ kú, ó sábà máa ń pe ìdílé ẹ̀ jọ, kó lè sọ ohun tó fẹ́ kí wọ́n ṣe. (Àìsá. 38:1) Ó lè jẹ́ ìgbà yẹn ló máa yan ẹni tó máa jẹ́ olórí ìdílé tóun bá ti kú.
Nígbà tí Jékọ́bù fẹ́ kú, ó ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọkùnrin ẹ̀ méjìlá (12) lọ́jọ́ iwájú (Wo ìpínrọ̀ 1-2)
3. Kí nìdí tí ohun tí Jékọ́bù sọ ní Jẹ́nẹ́sísì 49:1, 2 fi ṣe pàtàkì?
3 Ka Jẹ́nẹ́sísì 49:1, 2. Ìpàdé tí Jékọ́bù bá àwọn ọmọ ẹ̀ ṣe yìí ṣàrà ọ̀tọ̀. Wòlíì ni Jékọ́bù lásìkò yẹn torí pé níbi ìpàdé náà, Jèhófà fi ẹ̀mí ẹ̀ darí ẹ̀ kó lè sọ àwọn nǹkan pàtàkì tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń pe ohun tó bá àwọn ọmọ ẹ̀ sọ ní “àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nígbà tó fẹ́ kú.”
4. Kí la máa kọ́ bá a ṣe ń gbé àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nígbà tó fẹ́ kú yẹ̀ wò? (Tún wo àpótí náà “Ìdílé Jékọ́bù.”)
4 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí Jékọ́bù sọ fún mẹ́rin lára àwọn ọmọ ẹ̀, ìyẹn Rúbẹ́nì, Síméónì, Léfì àti Júdà. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò nǹkan tí Jékọ́bù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀ mẹ́jọ tó kù. A máa rí i pé Jékọ́bù ò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ ẹ̀ nìkan, ó tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀ tó máa di orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó bá yá. Bá a ṣe ń gbé ìtàn orílẹ̀-èdè náà yẹ̀ wò, a máa rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ ṣẹ. Tá a bá gbé àwọn nǹkan tó sọ yẹ̀ wò dáadáa, a máa kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì táá jẹ́ ká máa ṣe ohun tí Jèhófà Baba wa ọ̀run fẹ́.
RÚBẸ́NÌ
5. Kí ni Rúbẹ́nì rò pé bàbá òun máa fún òun?
5 Rúbẹ́nì ni Jékọ́bù kọ́kọ́ bá sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ni àkọ́bí mi.” (Jẹ́n. 49:3) Torí pé òun ni àkọ́bí, ó ṣeé ṣe kí Rúbẹ́nì rò pé ogún tí bàbá òun máa fún òun máa ju tàwọn tó kù lọ. Ó tún ṣeé ṣe kó máa rò pé òun lòun máa di olórí ẹbí tí bàbá òun bá kú, kí àwọn àtọmọdọ́mọ òun sì máa ní àǹfààní yẹn lọ.
6. Kí nìdí tí Rúbẹ́nì fi pàdánù ẹ̀tọ́ àkọ́bí tó ní? (Jẹ́nẹ́sísì 49:3, 4)
6 Rúbẹ́nì pàdánù ẹ̀tọ́ àkọ́bí tó ní. (1 Kíró. 5:1) Kí nìdí? Ọdún díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, ó bá Bílíhà tó jẹ́ wáhàrì bàbá rẹ̀ sùn. Bílíhà ni ìránṣẹ́bìnrin Réṣẹ́lì, Jékọ́bù sì fẹ́ràn Réṣẹ́lì ìyàwó ẹ̀ gan-an kó tó kú. (Jẹ́n. 35:19, 22) Líà ló bí Rúbẹ́nì, òun sì ni ìyàwó míì tí Jékọ́bù fẹ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ló gba Rúbẹ́nì lọ́kàn tó fi bá Bílíhà sùn. Ó sì lè jẹ́ pé ìdí tó fi bá Bílíhà sùn ni pé ó fẹ́ kí bàbá òun kórìíra ẹ̀ kó lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ìyá òun. Èyí ó wù ó jẹ́, inú Jèhófà ò dùn sóhun tó ṣe yẹn, inú bàbá ẹ̀ náà ò sì dùn.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 49:3, 4.
7. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Rúbẹ́nì àtàwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀? (Tún wo àpótí náà “Àsọtẹ́lẹ̀ Tí Jékọ́bù Sọ Nígbà Tó Fẹ́ Kú.”)
7 Jékọ́bù sọ fún Rúbẹ́nì pé: “O ò ní ta yọ.” Ohun tí Jékọ́bù sọ yìí ṣẹ. Kò sí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé àwọn àtọmọdọ́mọ Rúbẹ́nì di ọba, àlùfáà tàbí wòlíì. Síbẹ̀, Jékọ́bù ò kọ Rúbẹ́nì lọ́mọ, àwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀ sì di ọ̀kan lára ẹ̀yà Ísírẹ́lì. (Jóṣ. 12:6) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Rúbẹ́nì níwà tó dáa, kò sì sí àkọsílẹ̀ tó fi hàn pé ó tún ṣèṣekúṣe lẹ́yìn ìgbà yẹn.—Jẹ́n. 37:20-22; 42:37.
8. Kí la kọ́ lára Rúbẹ́nì?
8 Ohun tá a kọ́. Ó yẹ ká ṣiṣẹ́ kára láti máa kó ara wa níjàánu, ká sì sá fún ìṣekúṣe. Tó bá ń ṣe wá bíi pé ká dẹ́ṣẹ̀, ó yẹ ká ronú nípa bí ẹ̀ṣẹ̀ náà ṣe máa dun Jèhófà, àwọn ará ilé wa àtàwọn míì. Ó tún yẹ ká rántí pé “ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.” (Gál. 6:7) Yàtọ̀ síyẹn, bí Jèhófà ṣe bójú tó ọ̀rọ̀ Rúbẹ́nì jẹ́ ká rí i pé aláàánú ni Jèhófà. Síbẹ̀, Jèhófà ò ní sọ pé ká má jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wa, àmọ́ tá a bá ronú pìwà dà tá a sì ń ṣohun tó tọ́, Jèhófà máa dárí jì wá, á sì bù kún wa.
SÍMÉÓNÌ ÀTI LÉFÌ
9. Kí nìdí tí inú Jékọ́bù ò fi dùn sí Síméónì àti Léfì? (Jẹ́nẹ́sísì 49:5-7)
9 Ka Jẹ́nẹ́sísì 49:5-7. Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù bá Síméónì àti Léfì sọ̀rọ̀, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé inú òun ò dùn sí wọn. Ṣáájú ìgbà yẹn, ọkùnrin ará Kénáánì kan tó ń jẹ́ Ṣékémù fipá bá Dínà ọmọbìnrin Jékọ́bù lò pọ̀. Ká sòótọ́, inú gbogbo ọmọkùnrin Jékọ́bù ni ò dùn sóhun tí ọkùnrin yẹn ṣe, àmọ́ Síméónì àti Léfì hùwà ìkà. Wọ́n parọ́ fáwọn ará Ṣékémù pé tí àwọn ọkùnrin wọn bá dádọ̀dọ́, àwọn máa ṣe nǹkan tí wọ́n fẹ́. Àwọn ọkùnrin náà sì gbà. Lẹ́yìn tí wọ́n dádọ̀dọ́ tí wọ́n sì ń jẹ̀rora, Síméónì àti Léfì “mú idà wọn, wọ́n yọ́ lọ sí ìlú náà, wọ́n sì pa gbogbo ọkùnrin” tó wà níbẹ̀.—Jẹ́n. 34:25-29.
10. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ fún Síméónì àti Léfì ṣe ṣẹ? (Tún wo àpótí náà “Àsọtẹ́lẹ̀ Tí Jékọ́bù Sọ Nígbà Tó Fẹ́ Kú.”)
10 Ìwà ìkà tí Síméónì àti Léfì hù yìí ba Jékọ́bù nínú jẹ́ gan-an. Jékọ́bù sọ tẹ́lẹ̀ nípa wọn pé àwọn ọmọ wọn máa fọ́n ká sáàárín Ísírẹ́lì. Ó lé ní igba (200) ọdún kí àsọtẹ́lẹ̀ yìí tó ṣẹ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti wọ Ilẹ̀ Ìlérí nígbà yẹn. Wọ́n fún ẹ̀yà Síméónì ní ilẹ̀ wọn, àwọn ilẹ̀ náà sì wà káàkiri ilẹ̀ ẹ̀yà Júdà. (Jóṣ. 19:1) Ìlú méjìdínláàádọ́ta (48) ni ogún táwọn ọmọ Léfì gbà, àwọn ìlú náà sì wà káàkiri ilẹ̀ Ísírẹ́lì.—Jóṣ. 21:41.
11. Àwọn ohun rere wo ni ẹ̀yà Síméónì àti Léfì ṣe?
11 Àwọn àtọmọdọ́mọ Síméónì àti Léfì ò ṣe irú àṣìṣe táwọn baba ńlá wọn ṣe. Ìdí ni pé ẹ̀yà Léfì fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn mímọ́. Nígbà tí Mósè lọ gba Òfin lọ́wọ́ Jèhófà lórí Òkè Sínáì, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn ère ọmọ màlúù, àmọ́ àwọn ọmọ Léfì ò dara pọ̀ mọ́ wọn, ṣe ni wọ́n ran Mósè lọ́wọ́ láti mú ìwà burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà. (Ẹ́kís. 32:26-29) Torí náà, Jèhófà ya ẹ̀yà Léfì sọ́tọ̀ pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ àlùfáà ní Ísírẹ́lì. (Ẹ́kís. 40:12-15; Nọ́ń. 3:11, 12) Nígbà tó yá tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gba Ilẹ̀ Ìlérí, àwọn ọmọ Síméónì náà ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, wọ́n ran ẹ̀yà Júdà lọ́wọ́ láti bá àwọn ọ̀tá jà kí wọ́n lè gba ogún wọn.—Oníd. 1:3, 17.
12. Kí la kọ́ lára Síméónì àti Léfì?
12 Ohun tá a kọ́. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìbínú mú ká ṣe ìpinnu tí kò tọ́ tàbí hùwà tí ò dáa. Kò sẹ́ni tí ò lè bínú tí wọ́n bá hùwà tí ò dáa sí i tàbí sí èèyàn ẹ̀. (Sm. 4:4) Àmọ́, ó yẹ ká rántí pé inú Jèhófà ò ní dùn sí wa tá a bá ń fìbínú sọ̀rọ̀ sáwọn èèyàn tàbí ṣe ohun tí ò dáa sí wọn. (Jém. 1:20) Táwọn ará tàbí àwọn tí kì í ṣe ìránṣẹ́ Jèhófà bá rẹ́ wa jẹ, ó yẹ ká fi ìlànà Bíbélì yanjú ọ̀rọ̀ náà, ìyẹn ò ní jẹ́ ká bínú ju bó ṣe yẹ lọ débi tọ́rọ̀ náà á fi wá di wàhálà. (Róòmù 12:17, 19; 1 Pét. 3:9) Tó o bá jẹ́ ọmọ, táwọn òbí ẹ sì ń ṣe ohun tínú Jèhófà ò dùn sí, kò yẹ kó o tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Má sì rò pé o ò ní lè ṣe ohun táá múnú Jèhófà dùn. Ó dájú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe ohun tó tọ́.
JÚDÀ
13. Kí nìdí tí ẹ̀rù fi lè máa ba Júdà nígbà tí bàbá ẹ̀ fẹ́ bá a sọ̀rọ̀?
13 Júdà ni Jékọ́bù fẹ́ bá sọ̀rọ̀ báyìí. Lẹ́yìn tí Jékọ́bù sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹ̀gbọ́n Júdà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó ṣeé ṣe kẹ́rù máa bà á. Ìdí sì ni pé òun náà ti ṣe àwọn àṣìṣe kan. Ó dájú pé ó wà lára àwọn ọmọ Jékọ́bù yòókù tó lọ kó ohun ìní àwọn ará ìlú Ṣékémù. (Jẹ́n. 34:27) Lẹ́yìn náà, òun àtàwọn arákùnrin ẹ̀ jọ ta Jósẹ́fù sóko ẹrú, wọ́n sì parọ́ fún bàbá wọn. (Jẹ́n. 37:31-33) Nígbà tó yá, ó bá Támárì ìyàwó ọmọ ẹ̀ sùn torí ó rò pé aṣẹ́wó ni.—Jẹ́n. 38:15-18.
14. Àwọn nǹkan rere wo ni Júdà ṣe? (Jẹ́nẹ́sísì 49:8, 9)
14 Láìka gbogbo ohun tí Júdà ṣe yìí sí, ẹ̀mí Ọlọ́run darí Jékọ́bù láti gbóríyìn fún un, ó sì sọ pé ọjọ́ ọ̀la ẹ̀ máa dáa. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 49:8, 9.) Ìdí ni pé Júdà tọ́jú bàbá ẹ̀ tó ti darúgbó yìí gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, ó fi inúure hàn sí Bẹ́ńjámínì tó jẹ́ àbígbẹ̀yìn bàbá wọn nígbà tó gbà kí wọ́n mú òun lẹ́rú dípò ẹ̀.—Jẹ́n. 44:18, 30-34.
15. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nípa Júdà ṣe ṣẹ?
15 Jékọ́bù sọ tẹ́lẹ̀ pé Júdà máa múpò iwájú láàárín àwọn arákùnrin ẹ̀. Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ yìí pẹ́ kó tó ṣẹ. Ó tó nǹkan bí igba (200) ọdún lẹ́yìn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn kí ẹ̀yà Júdà tó múpò iwájú lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Nígbà tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì, ẹ̀yà Júdà ló wà níwájú nínú aginjù bí wọ́n ṣe ń lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. (Nọ́ń. 10:14) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí wọ́n fẹ́ gba Ilẹ̀ Ìlérí, Júdà ló kọ́kọ́ lọ bá àwọn ọ̀tá jà. (Oníd. 1:1, 2) Bákan náà, látinú ẹ̀yà Júdà, Dáfídì ni ọba àkọ́kọ́ tó jẹ lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká wo bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ láwọn ọ̀nà míì.
16. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 49:10 ṣe ṣẹ? (Tún wo àpótí náà “Àsọtẹ́lẹ̀ Tí Jékọ́bù Sọ Nígbà Tó Fẹ́ Kú.”)
16 Jékọ́bù sọ tẹ́lẹ̀ pé Ẹni tó máa ṣàkóso ayé títí láé máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Júdà. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 49:10 àti àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) Jésù Kristi ni Alákòóso yẹn, òun ni Jékọ́bù pè ní Ṣílò. Áńgẹ́lì kan sọ nípa Jésù pé: ‘Jèhófà Ọlọ́run máa fún un ní ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀.’ (Lúùkù 1:32, 33) Bíbélì tún pe Jésù ní “Kìnnìún ẹ̀yà Júdà.”—Ìfi. 5:5.
17. Báwo la ṣe lè máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn wò wọ́n?
17 Ohun tá a kọ́. Lóòótọ́ Júdà ṣe àwọn àṣìṣe kan, síbẹ̀ Jèhófà ṣojú rere sí i. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kí àwọn arákùnrin Júdà máa bi ara wọn pé kí ni Jèhófà rí lára ẹ̀ tó fi ṣojúure sí i? Ohun yòówù kí wọ́n máa rò, Jèhófà rí ohun tó dáa lára Júdà, ó sì ṣojúure sí i. Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà? Tí wọ́n bá fún arákùnrin tàbí arábìnrin kan ní iṣẹ́ ìsìn pàtàkì kan, a lè rò pé àǹfààní yẹn ò tọ́ sẹ́ni náà torí pé a mọ àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ní. Àmọ́, ó yẹ ká máa rántí pé Jèhófà mọyì àwọn ànímọ́ tó dáa tó ní. Ibi tá a dáa sí ni Jèhófà máa ń wò. Torí náà, ó yẹ ká fara wé e.
18. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ní sùúrù?
18 Nǹkan míì tá a kọ́ lára Júdà ni pé ká máa ní sùúrù. Ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ, àmọ́ ó lè má jẹ́ bá a ṣe fẹ́ tàbí ní àkókò tá a fẹ́. Bó ṣe rí fáwọn àtọmọdọ́mọ Júdà nìyẹn, kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àmọ́ wọ́n fara mọ́ àwọn tí Jèhófà yàn pé kí wọ́n jẹ́ aṣáájú, irú bíi Mósè tó wá láti ẹ̀yà Léfì, Jóṣúà tó wá láti ẹ̀yà Éfúrémù àti Ọba Sọ́ọ̀lù tó wá láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì. Ó yẹ káwa náà fara mọ́ àwọn tí Jèhófà yàn pé kí wọ́n máa bójú tó wa lónìí.—Héb. 6:12.
19. Kí la kọ́ lára Jèhófà nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nígbà tó fẹ́ kú?
19 Kí làwọn nǹkan tá a ti kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nígbà tó fẹ́ kú? A ti rí i pé “ọ̀nà tí èèyàn gbà ń wo nǹkan kọ́ ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan.” (1 Sám. 16:7) Jèhófà máa ń ní sùúrù, ó sì máa ń dárí jì wá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ò gba ìwà tí ò dáa láyè, kì í retí pé káwa ìránṣẹ́ ẹ̀ ṣe nǹkan lọ́nà pípé. Kódà, ó máa ń ṣojúure sáwọn tó ṣàṣìṣe ńlá tí wọ́n bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó tọ́. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò nǹkan tí Jékọ́bù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀ mẹ́jọ tó kù.
ORIN 124 Jẹ́ Adúróṣinṣin