Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 5
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 5
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 2 ìpínrọ̀ 15 sí 20 àti àpótí ojú ìwé 23
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 16-18
No. 1: 1 Sámúẹ́lì 18:1-16
No. 2: Ṣé Orí Àgbélébùú Ni Jésù Kú Sí? (td 2A)
No. 3: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Tẹ̀ Lé Ipa Ọ̀nà Aájò Àlejò? (Róòmù 12:13)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Bí Onílé Bá Sọ Pé, ‘Èmi Kò Nífẹ̀ẹ́ sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.’ Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Àwọn Ìjíròrò Bíbélì Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 9 sí 10.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Pa Dà Lọ Bẹ Àwọn Tó Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi Wò. Àsọyé. Sọ iye àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi àtàwọn ìrírí tẹ́ ẹ ní. Gba gbogbo àwọn ará níyànjú láti bẹ àwọn olùfìfẹ́hàn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi wò, kí wọ́n sì ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí wọ́n tún ké sí wọn láti wá gbọ́ àkànṣe àsọyé. Ṣe àṣefihàn kan tó dá lórí bí akéde kan ṣe ń ké sí ẹnì kan wá síbi àkànṣe àsọyé.