Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní March: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Kí àwọn akéde ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí onílé bá gba ìwé yìí tàbí tó bá ti ní in lọ́wọ́. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn tó fi mọ́ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ míì tí ètò Ọlọ́run ṣètò, àmọ́ tí wọn kò tíì máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé, ẹ fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Kẹ́ ẹ sì ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn. June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ fún un ní ìwé èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́.
◼ Ọjọ́ Tuesday, March 30, 2010 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Orin 8 àti 109 láti inú ìwé orin wa tuntun ni kẹ́ ẹ lò. Tó bá jẹ́ ọjọ́ Tuesday ni ìjọ yín máa ń ṣèpàdé, kẹ́ ẹ gbìyànjú láti ṣe é ní ọjọ́ míì lọ́sẹ̀ yẹn. Tó bá sì jẹ́ pé àwọn ìjọ tó ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba yín pọ̀ débi pé kò sáyè láti ṣe ìpàdé yín lọ́jọ́ míì, ẹ lè fagi lé ìpàdé náà. Kẹ́ ẹ fi àwọn apá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tẹ́ ẹ bá rí i pé ó kan ìjọ yín gbọ̀ngbọ̀n kún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn míì.