Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Inú wa dùn láti sọ fún yín pé ẹgbàá mọ́kàndínláàádọ́jọ, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún àti mọ́kàndínlógún [298,919] làwọn akéde tó ròyìn ní oṣù kejì ọdún iṣẹ́ ìsìn tuntun. Èyí sì ti mú kí ìpíndọ́gba akéde tó ń ròyìn ròkè sí ọ̀kẹ́ mẹ́rin lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàsán àti irínwó lé mọ́kànléláàádọ́rùn-ún [297,491], èyí fi ohun tó lé ní ìdá méjì nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ ju ìpíndọ́gba akéde tó ròyìn ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá.