ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/14 ojú ìwé 2
  • Má Ṣe Jẹ́ Alábàáṣiṣẹ́ Tí Kì Í Sọ̀rọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Ṣe Jẹ́ Alábàáṣiṣẹ́ Tí Kì Í Sọ̀rọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Ṣèrànwọ́ fún Ẹni Tẹ́ Ẹ Jọ Ń Wàásù Lóde Ẹ̀rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Bá A Ṣe Lè Máa Gbé Ara Wa Ró Lóde Ẹ̀rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Máa Fi Ìtara Wàásù Nìṣó
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Ṣèrànwọ́ fún Ẹni Tẹ́ Ẹ Jọ Ṣiṣẹ́ Lóde Ẹ̀rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
km 1/14 ojú ìwé 2

Má Ṣe Jẹ́ Alábàáṣiṣẹ́ Tí Kì Í Sọ̀rọ̀

1. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tá a bá ń bá àwọn míì ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí?

1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń ka àkókò tó bá fi wà pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ sí àkókò tí wọ́n lè fi fún ara wọn ní “pàṣípààrọ̀ ìṣírí.” (Róòmù 1:12) Tí ìwọ àti akéde kan bá jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, ṣé o máa ń lo àǹfààní yẹn láti fún un níṣìírí, kó o sì ràn án lọ́wọ́? Dípò tó o fi máa dákẹ́ láìbá ẹni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí sọ̀rọ̀, o ò ṣe sọ ohun tó sọ ẹ́ di akéde tó jáfáfá fún un?

2. Kí la lè ṣe láti ran ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ nígboyà, kí sì nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì?

2 Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ní Ìgboyà: Àwọn akéde kan kò ní ìgboyà, èyí sì lè hàn lójú wọn tàbí nínú ohùn wọn. A lè jẹ́ kí wọ́n ní ìgboyà tá a bá ń gbóríyìn fún wọn tọkàntọkàn. Àwọn ọ̀nà míì wo la lè gbà ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti ní ìgboyà? Alábòójútó arìnrìn-àjò kan kì í tijú láti sọ fún ẹni tí wọ́n bá jọ ṣiṣẹ́ nípa ohun tó máa ń ba òun lẹ́rù àti bí òun ṣe máa ń gbàdúrà léraléra kí Ọlọ́run lè ran òun lọ́wọ́ láti borí ìbẹ̀rù náà. Arákùnrin kan sọ ohun tó ran òun lọ́wọ́ tóun fi ní ìgboyà. Ó ní “Mo máa ń kọ́kọ́ rẹ́rìn-ín músẹ́. Nígbà míì, mo lè mọ ohun tí mo fẹ́ sọ, àmọ́ ó lè gba pé kí n gbàdúrà kí n tó lè sọ ọ́.” Ǹjẹ́ nǹkan kan wà tó ti jẹ́ kó o túbọ̀ ní ìgboyà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Sọ ohun náà fún ẹni tẹ́ ẹ jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí.

3. Kí la lè sọ fún ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tó lè ràn án lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?

3 Ẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Ọ̀nà Tẹ́ Ẹ Gbà Ń Wàásù: Ṣé ó ní ọ̀nà kan tó rọrùn tó o fi ń bẹ̀rẹ̀ ìwàásù lóde ẹ̀rí tó o sì rí i pé ó gbéṣẹ́? Ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ tó o máa ń kọ́kọ́ sọ tàbí ìbéèrè tó o máa ń béèrè, ó sì lè jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan ládùúgbò yín lo máa ń lò. Ṣé o ti sọ àwọn àbá nípa bá a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn lọni di ọ̀rọ̀ tara ẹ̀ tó o sì rí i pé ó gbéṣẹ́? Sọ àwọn nǹkan yìí fún ẹni tẹ́ ẹ jọ ṣiṣẹ́. (Òwe 27:17) Tẹ́ ẹ bá ń lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò, o lè sọ ohun tẹ́ ẹ fẹ́ ṣe tẹ́ ẹ bá débẹ̀ àti bẹ́ ẹ ṣe máa ṣe é. Tẹ́ ẹ bá kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tán, o lè ṣàlàyé ìdí tó o fi lo kókó kan, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó bá akẹ́kọ̀ọ́ náà mu.

4. Kí nìdí tó fi yẹ kó wù wá láti ran àwọn tá a jọ ń wàásù ìhìn rere lọ́wọ́?

4 Àwọn ajíhìnrere ní ọ̀rúndún kìíní máa ń ran àwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn wọ́n tún rí i pé ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà níbẹ̀ táwọn bá ń fún ara wọn níṣìírí, tí wọ́n sì ń fún ara wọn lókun. (Ìṣe 11:23; 15:32) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dá ọ̀dọ́kùnrin náà Tímótì lẹ́kọ̀ọ́, lẹ́yìn náà ó ní kó máa kọ́ àwọn míì láwọn ohun tó ti kọ́. (2 Tím. 2:2) Nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí, tá ò bá gbàgbé láti máa ṣe rere sí àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni, a máa fi kún ayọ̀ wọn, a máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí iṣẹ́ ìwàásù wọn lè túbọ̀ gbéṣẹ́, a sì tún máa mú inú Baba wa ọ̀run dùn.—Héb. 13:15, 16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́