Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 27
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 27
Orin 106 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 2 ìpínrọ̀ 1 sí 11 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 17-20 (10 min.)
No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 17:18–18:8 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ṣé O Dá Àwọn Wòlíì Èké Mọ̀?—td 44A (5 min.)
No. 3: Ọlọ́run Ní Orúkọ Kan—lr orí 4 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́. Àsọyé. Sọ ètò tí ìjọ ṣe fún jíjáde òde ẹ̀rí ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù February. Gba gbogbo àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà. Lo àbá tó wà lójú ìwé 4 láti ṣe àṣefihàn kan ní ṣókí.
15 min: Kí Ni Àwọn Àfojúsùn Rẹ Nípa Tẹ̀mí? Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 117, ìpínrọ̀ 1 títí dé ìparí orí yẹn. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣe àfojúsùn wọn, tí ọwọ́ wọn sì ti tẹ̀ ẹ́. Ìṣírí wo ni wọ́n rí gbà? Àwọn ìṣòro wo ni wọ́n borí? Àwọn ìbùkún wo ni wọ́n ti rí?
10 min: “Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Pẹ̀lú Àwọn Tó Ò Ń Fún Ní Ìwé Ìròyìn Déédéé.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹnì kan tí wọ́n ti máa ń fún ní ìwé ìròyìn.
Orin 103 àti Àdúrà