Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 20
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 20
Orin 34 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 1 ìpínrọ̀ 18 sí 23 àti àpótí tó wà lójú ìwé 14 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 11-16 (10 min.)
No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 14:17–15:11 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kò Sígbà Kan Tí Ayé Máa Pa Run—td 25B (5 min.)
No. 3: Ẹni Tí Ó Dá Ohun Gbogbo—lr orí 3 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Mátíù 7:6-11. Ẹ jíròrò bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
10 min: Ẹ Máa Bọ̀wọ̀ fún Àwọn Tí Ń Ṣiṣẹ́ Kára Láàárín Yín. (1 Tẹs. 5:12, 13) Ìjíròrò tó dá lórí àwọn ìbéèrè yìí: (1) Àwọn ọ̀nà wo làwọn alàgbà gbà ń ṣiṣẹ́ kára nínú ìjọ? (2) Báwo la ṣe lè máa ka àwọn alàgbà sí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀? (3) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fún àwọn tí ń mú ipò iwájú níṣìírí? (4) Báwo la ṣe lè fún àwọn alàgbà àtàwọn ìdílé wọn níṣìírí? (5) Báwo ni àwọn ará nínú ìjọ àtàwọn alàgbà ṣe máa ń jàǹfààní tá a bá ń ṣègbọràn sí àwọn tó ń mú ipò iwájú?
10 min: “Má Ṣe Jẹ́ Alábàáṣiṣẹ́ Tí Kì Í Sọ̀rọ̀.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ohun tí wọ́n kọ́ lọ́dọ̀ ẹnì kan tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tó sì ti ràn wọ́n lọ́wọ́.
Orin 93 àti Àdúrà