Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 14
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 14
Orin 114 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 5 ìpínrọ̀ 18 sí 21 àti àpótí tó wà lójú ìwé 55 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 11-14 (10 min.)
No. 1: Ẹ́kísódù 12:37-51 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Lílo Ère Ń Tàbùkù sí Ọlọ́run—td 9A (5 min.)
No. 3: Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dárí Jini—lr orí 14 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: Máa Lo Àwọn Nǹkan Tí Jèhófà Ti Pèsè fún Wa. Ìjíròrò tá a gbé ka Ìwé Ọdọọdún 2013, ojú ìwé 51, ìpínrọ̀ 3; ojú ìwé 55, ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 56, ìpínrọ̀ 1 àti ojú ìwé 116. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
15 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Ṣèrànwọ́ fún Ẹni Tẹ́ Ẹ Jọ Ṣiṣẹ́ Lóde Ẹ̀rí.” Ìjíròrò. Ṣe àṣefihàn méjì tó dá lórí bí ẹnì kan ò ṣe ran ẹni tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí lọ́wọ́. Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan ní kí àwọn ará sọ ohun tí ẹni náà ì bá ti ṣe láti ran ẹni tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ lọ́wọ́.
Orin 45 àti Àdúrà