Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 10
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 10
Orin 61 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 28 ìpínrọ̀ 18 sí 21, àti àpótí tó wà lójú ìwé 289 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 21-22 (8 min.)
No. 1: 1 Àwọn Ọba 22:13-23 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo Lo Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run?—igw ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 1 sí 4 (5 min.)
No. 3: Dènà Agbára Ìtannijẹ Ọrọ̀—Mát. 13:22 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.”—Jóṣ. 24:15.
10 min: “Ní Tèmi àti Agbo Ilé Mi, Jèhófà Ni Àwa Yóò Máa Sìn.” Àsọyé tó dá lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí. Ka Diutarónómì 6:6, 7; Jóṣúà 24:15 àti Òwe 22:6, kó o sì sọ bá a ṣe lè fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sílò. Tẹnu mọ́ ọn pé ó yẹ kí àwọn ọkọ tàbí àwọn bàbá máa mú ipò iwájú nínú àwọn nǹkan tẹ̀mí. Sọ àwọn nǹkan tí ètò Ọlọ́run pèsè tó lè ran àwọn ìdílé lọ́wọ́. Mẹ́nu ba díẹ̀ lára àwọn apá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn oṣù yìí, kó o sì sọ bó ṣe tan mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí.
20 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bó O Ṣe Lè Dá Àwọn Ẹni Tuntun Lẹ́kọ̀ọ́.” Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí àwọn òbí ṣe lè fi ìtọ́ni tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ṣe àṣefihàn bàbá kan tí òun àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin ń múra bí wọ́n á ṣe gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lóde ẹ̀rí sílẹ̀.
Orin 93 àti Àdúrà