Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Inú wa dùn láti fi ìròyìn nípa àsọyé tí Aṣojú Orílé-iṣẹ́ sọ ní March 1, 2015 tó yín létí. A ṣe àtagbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí sí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé mẹ́tàdínláàádọ́ta [1,847] àtàwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ méjìlélógún [22]. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tá a gbé irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí jáde fún ọ̀pọ̀ èèyàn lórílẹ̀-èdè yìí. Àwọn èèyàn tó gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí jẹ́ ogún ọ̀kẹ́ ó lé kan àti mẹ́ta [401,003]. Jèhófà ni ìyìn yẹ fún àṣeyọrí ńlá yìí tó wáyé nínú ètò Ọlọ́run.