Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Ilé Ìṣọ́ August 1
“A wá ṣèbẹ̀wò ráńpẹ́ sọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò wa ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro kan tó kan gbogbo èèyàn. Ikú ẹni tá a fẹ́ràn wà lára àwọn ìṣòro tá a máa ń ní. Ṣé ìwọ náà gbà bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ìlérí Ọlọ́run yìí tó wà nínú Bíbélì. [Ka Ìṣípayá 21:3, 4.] Bíbélì jẹ́ ká nírètí pé àwọn èèyàn wa tó ti kú máa jíǹde lọ́jọ́ kan. Ìwé ìròyìn yìí sọ bí èyí ṣe máa ṣẹlẹ̀.”
Ji! July–August
“Lóde òní, kì í rọrùn fáwọn òbí láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè jẹ́ onígbọràn. Ṣé ẹ mọ ìdí tí kò fi rọrùn? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì sọ ìdí tó fi yẹ kí àwọn ọmọ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí wọn lẹ́nu. [Ka Òwe 29:15.] Báwo làwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa gbọ́ràn? Kí ló yẹ kí àwọn òbí yẹra fún? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí wà ní ojú ìwé 8 àti 9 nínú ìwé ìròyìn yìí. Àwọn ìdáhùn yìí á jẹ́ kí àwọn òbí mọ bí wọ́n ṣe lè fi ìfẹ́ bá àwọn ọmọ wọn wí lọ́nà tó yẹ tí èyí á sì jẹ́ kí àwọn ọmọ náà wúlò tí wọ́n bá dàgbà.”