Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Ilé Ìṣọ́ June 1
“A wá ṣèbẹ̀wò ráńpẹ́ sọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò wa ká lè sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní ti sọ Bíbélì di ìwé tí kò bágbà mu. Kí lèrò rẹ nípa Bíbélì? Ǹjẹ́ o rò pé ó yẹ ká fọkàn tán ohun tí Bíbélì bá sọ? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé ohun tí Bíbélì sọ bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu. [Ka Jóòbù 26:7.] Ìwé ìròyìn yìí fi hàn pé ohun tí Bíbélì sọ bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu, wọn ò sì ta kora wọn.”
Ji! May–June
“Ó máa ń ṣòro fún àwọn tọkọtaya kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó láti mọ èwo làkọ́kọ́ nínú ọkọ tàbí aya wọn àti àwọn òbí wọn. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí ṣe kedere. [Ka Mátíù 19:5.] Tí àwọn tọkọtaya bá fi sọ́kàn pé ìdílé tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ni àwọn jẹ́, èyí á jẹ́ kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún ètò yìí. Wọ́n á sì lè fi ọ̀rọ̀ ẹnì kejì wọn ṣáájú, tí wọ́n á sì tún ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn àna wọn.” Wàá rí àwọn àbá tó máa ran ọ́ lọ́wọ́ nínú àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 8 àti 9 ìwé ìròyìn yìí.