Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Ilé Ìṣọ́ January 1
“Ó jọ pé ìwà ìbàjẹ́ àwọn alákòóso ti wá di ìṣòro ńlá báyìí. Kí lẹ rò pé ó fà á? [Jẹ́ kó fèsì.] Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ kan tí mo kà nínú Bíbélì tó gbà mì lọ́kàn. [Ka Oníwàásù 7:20.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa ṣe láti fòpin sí ìwà ìbàjẹ́. Ẹ jọ̀wọ́, mo fẹ́ kí ẹ kà á. Ẹ̀dà tiyín rèé.”
Ji! January–February
“Gbogbo èèyàn ló fẹ́ láyọ̀, àmọ́ lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò tiẹ̀ láyọ̀ rárá. Kí lẹ rò pé a lè ṣe tí a ó fi ní ojúlówó ayọ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti ní ìdílé aláyọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ìlànà Bíbélì yìí. [Ka Hébérù 13:5.] Ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ nípa ohun mẹ́rin tí Bíbélì sọ pé èèyàn lè ṣe láti ní ojúlówó ayọ̀.”