Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Saturday Àkọ́kọ́ Lóṣù July
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Àdúrà Olúwa yìí ní àsọtúnsọ: ‘Kí ìjọba rẹ dé. Ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe ní ayé bí wọ́n ti ń ṣe é ní ọ̀run.’ Ìjọba wo lo rò pé Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Ẹsẹ ìwé Mímọ́ tí mo fẹ́ kà yìí sọ ohun kan fún wa nípa rẹ̀.” Ka Dáníẹ́lì 2:44. Kó o wá mú Ilé Ìṣọ́ July 1 fún onílé náà, kẹ́ ẹ jọ ka àwọn ìsọfúnni tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́ lójú ìwé 16, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ July 1
“Torí pé ìgbésí ayé àwa èèyàn kúrú, tó sì kún fún onírúurú ìṣòro, ọ̀pọ̀ ló máa ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tá a fi wà láyé. Ǹjẹ́ o ti ronú nípa ìdí tá a fi wà láyé rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì ṣèlérí pé báyìí kọ́ ni yóò ṣe máa rí lọ. [Ka Ìṣípayá 21:4.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe sí ayé yìí, ó sì tún sọ díẹ̀ lára ohun tí àwa fúnra wa lè ṣe láti mú kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀ nísinsìnyí.”
Ji! July–September
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń sọ pé ibi gbogbo ni Ọlọ́run wà, ó sì wà nínú ohun gbogbo. Kí ni èrò tìrẹ nípa ọ̀rọ̀ yìí? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka 1 Ọba 8:39.] Àpilẹ̀kọ yìí tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 24, sọ ìdí tí Ọlọ́run kò fi ní láti máa wà ní ibi gbogbo.”