ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/11 ojú ìwé 24-25
  • Ṣé Ibi Gbogbo Ni Ọlọ́run Wà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ibi Gbogbo Ni Ọlọ́run Wà?
  • Jí!—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìran Kíkàmàmà Kan
  • Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Wà Níbi Gbogbo Nígbà Gbogbo?
  • Ǹjẹ́ Ọlọ́run Ní Ibì Kan Tó Ń Gbé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ṣé Ibi Gbogbo Ni Ọlọ́run wà?
    Jí!—2005
  • Ṣé Ibi Gbogbo Ni Ọlọ́run Wà?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ògo Ìtẹ́ Jèhófà ní Ọ̀run
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 7/11 ojú ìwé 24-25

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Ibi Gbogbo Ni Ọlọ́run Wà?

Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé ibi gbogbo ni Ọlọ́run máa ń wà, ó sì máa ń wà nínú ohun gbogbo. Sólómọ́nì Ọlọ́gbọ́n Ọba béèrè lọ́wọ́ Jèhófà pé: “Ǹjẹ́ kí ìwọ fúnra rẹ gbọ́ ní ibi tí o ń gbé, ní ọ̀run. (1 Àwọn Ọba 8:30, 39) Bí Bíbélì ṣe sọ, Jèhófà Ọlọ́run ní ibi tó ń gbé. Sólómọ́nì pe ibẹ̀ ní “ọ̀run.” Àmọ́, kí ni ìyẹn túmọ̀ sí?

Nígbà míì, Bíbélì máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run” àti “àwọn ọ̀run” láti tọ́ka sí àwọn nǹkan tó wà lójú sánmà. (Jẹ́nẹ́sísì 2:1, 4) Àmọ́, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo, ó ní láti jẹ́ pé ibùgbé rẹ̀ ti wà kó tó dá ayé àti àwọn nǹkan tó wà lójú sánmà. Torí náà, á jẹ́ pé ibi téèyàn ò lè fojú rí ni Ọlọ́run ń gbé. Fún ìdí yìí, nígbà tí Bíbélì bá sọ pé ọ̀run ni ibùgbé Jèhófà Ọlọ́run, kì í ṣe ibì kan lójú ọ̀run tàbí ní gbalasa òfúrufú ló ń tọ́ka sí, bí kò ṣe ibùgbé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí.

Ìran Kíkàmàmà Kan

Bíbélì jẹ́ ká rí ohun tó fani lọ́kàn mọ́ra nípa bí ibùgbé Jèhófà ṣe rí nípasẹ̀ ìran kan tó fi han àpọ́sítélì Jòhánù. Nínú ìran yẹn, Jòhánù rí ilẹ̀kùn kan tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run, lẹ́yìn náà ó gbọ́ ohùn kan tó sọ fún un pé: “Máa bọ̀ lókè níhìn-ín.”—Ìṣípayá 4:1.

Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni Jòhánù wá rí ìran kíkàmàmà kan nípa Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀. Díẹ̀ rèé lára ohun tó rí: “Ìtẹ́ kan wà ní ipò rẹ̀ ní ọ̀run . . . Ẹni tí ó jókòó, ní ìrísí, sì dà bí òkúta jásípérì àti òkúta aláwọ̀ pupa tí ó ṣeyebíye, àti yí ká ìtẹ́ náà òṣùmàrè kan wà tí ó dà bí òkúta émírádì ní ìrísí. . . . Mànàmáná àti ohùn àti ààrá sì ń jáde wá láti inú ìtẹ́ náà . . . Àti níwájú ìtẹ́ náà ni ohun tí a lè pè ní òkun bí gíláàsì, tí ó dà bí kírísítálì wà.”—Ìṣípayá 4:2-6.

Èyí jẹ́ àpèjúwe ẹwà Jèhófà tó bùáyà àti ọlá ńlá rẹ̀ tí kò láfiwé. Tún wá kíyèsí àwọn nǹkan tó wà ní àyíká ìtẹ́ Jèhófà. Òṣùmàrè tó wà níbẹ̀ fi hàn pé ibẹ̀ pa rọ́rọ́, aláàfíà sì wà níbẹ̀. Mànàmáná, ohùn àti ààrá fi agbára Ọlọ́run hàn. Òkun bíi gíláàsì pe àfiyèsí wa sí bí àwọn tó wà níwájú Ọlọ́run ṣe ní ìdúró òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun ìṣàpẹẹrẹ ni àwọn nǹkan tí Jòhánù rí nínú ìran yìí, síbẹ̀, wọ́n jẹ́ ká mọ púpọ̀ nípa ibùgbé Ọlọ́run. Gbogbo nǹkan tí Jèhófà ńṣe ní ọ̀run ló wà létòlétò lọ́nà pípé. Kò sí ìdàrúdàpọ̀ ní ibùgbé Ọlọ́run.

Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Wà Níbi Gbogbo Nígbà Gbogbo?

Bí Ọlọ́run ṣe ní ibùgbé fi hàn pé kì í wà ní ibi gbogbo nígbà gbogbo. Báwo ló ṣe wá máa ń mọ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀? (2 Kíróníkà 6:39) Ọ̀nà kan jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tàbí ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run. Onísáàmù kan kọ̀wé pé: “Ibo ni mo lè lọ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀mí rẹ, ibo sì ni mo lè fẹsẹ̀ fẹ lọ kúrò ní ojú rẹ? Bí mo bá gòkè re ọ̀run, ibẹ̀ ni ìwọ yóò wà; bí mo bá sì ga àga ìrọ̀gbọ̀kú mi ní Ṣìọ́ọ̀lù, wò ó! ìwọ yóò wà níbẹ̀.”—Sáàmù 139:7-10.

Ká lè lóye bí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe wà níbi gbogbo, jẹ́ ká fi oòrùn ṣe àpẹẹrẹ. Ojú kan ló máa ń wà, àmọ́ kò síbi tí agbára rẹ̀ kò dé lórí ilẹ̀ ayé. Bákan náà, Jèhófà Ọlọ́run ní ibi tó ń gbé. Àmọ́, o lè ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé. Síwájú sí i, Jèhófà lè lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ibikíbi àti ní ìgbàkigbà. Ìdí nìyẹn tí 2 Kíróníkà 16:9 fi sọ pé: “Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.”

Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tá a mọ̀ sí ańgẹ́lì tí wọ́n wà létòlétò tún wà níkàáwọ́ Ọlọ́run. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ló wà lọ́run.a (Dáníẹ́lì 7:10) Ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ ló wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé àwọn ańgẹ́lì ń ṣojú fún Ọlọ́run, wọ́n wá sí ayé, wọ́n bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, wọ́n sì pa dà lọ jíṣẹ́ fún Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, nígbà ayé Ábúráhámù, àwọn ańgẹ́lì wá ṣèwádìí igbe ìráhùn nípa Sódómù àti Gòmórà. Kò sí àní-àní pé ìgbà tí àwọn ańgẹ́lì yẹn pa dà lọ jábọ̀ fún Ọlọ́run ni Ọlọ́run wá pinnu láti pa àwọn ìlú wọ̀nyẹn run.—Jẹ́nẹ́sísì 18:20, 21, 33; 19:1, 13.

Torí náà, Bíbélì fi hàn pé kò sídìí tí Jèhófà fúnra rẹ̀ á fi máa wà níbi gbogbo. Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti àwọn ańgẹ́lì alágbára, ó ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀.

Ó ṣe kedere pé Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ Ẹlẹ́dàá wa dáradára sí i. Inú Bíbélì la ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run ní ibi tó ń gbé, ibi tí a ń pè ní ọ̀run, ìyẹn ni ibùgbé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí níbi tí a ò lè fi ojú wa rí. Ẹgbẹẹgbàárùn àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ló sì ń gbé pẹ̀lú rẹ̀ ní ibùgbé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yìí. Àwọn ohun pàtàkì tó gbàfiyèsí níbẹ̀ ni ìparọ́rọ́, agbára àti ìjẹ́mímọ́. Bíbélì mú kó dá wa lójú pé tó ba tó àkókò lójú Ọlọ́run, aráyé máa gbádùn aláàfíà, irú èyí tó wà lọ́run, lórí ilẹ̀ ayé.—Mátíù 6:10.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìṣípayá 5:11 ṣàpèjúwe àwọn ańgẹ́lì tó wà láyìíká ìtẹ́ Ọlọ́run pé wọ́n jẹ́ “ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún.” Ẹgbàárùn-ún (10,000) lọ́nà ẹgbàárùn-ún (10,000) jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) mílíọ̀nù. Síbẹ̀, ẹsẹ Bíbélì yìí lo gbólóhùn náà “ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún,” tó fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ló wà lọ́run.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Ṣé ibi gbogbo ni Ọlọ́run wà?—1 Àwọn Ọba 8:30, 39.

● Báwo ni ibi tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lè dé ṣe gbòòrò tó?—Sáàmù 139:7-10.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 25]

Ojú kan ni oòrùn wà, àmọ́ kò síbi tí agbára rẹ̀ kò dé lórí ilẹ̀ ayé. Bákan náà, Ọlọ́run ní ibi tó ń gbé, àmọ́ a lè rí ọwọ́ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ níbikíbi tó bá fẹ́ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́