ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/13 ojú ìwé 4
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
km 6/13 ojú ìwé 4

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù July

“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló fẹ́ pẹ́ láyé tí wọ́n sì fẹ́ láyọ̀. Lójú tìrẹ, ǹjẹ́ o rò pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn dókítà lè mú kéèyàn wà láàyè títí láé? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo ohun tí ìwé yìí sọ.” Fi ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ July 1 hàn án, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àlàyé tó wà lábẹ́ ìbéèrè àkọ́kọ́ àti ẹsẹ Bíbélì kan, ó kéré tán. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìbéèrè tó kàn.

Àkíyèsí: Kí ẹ ṣe àṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yìí nígbà ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá tẹ́ ẹ máa ṣe ní July 6.

Ilé Ìṣọ́ July 1

“Ọ̀pọ̀ èèyàn tá a bá pàdé ló ní ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe. Àmọ́ àwọn kan sọ pé àwọn ò fọkàn tán ẹ̀sìn kankan mọ́. Ǹjẹ́ ìwọ rò pé a ṣì lè fọkàn tán ẹ̀sìn kankan. [Jẹ́ kó fèsì.] Jésù sọ ohun tó lè jẹ́ ká mọ ẹ̀sìn tòótọ́. [Ka Lúùkù 6:44a.] Ìwé yìí sọ àwọn àmì tá a lè fi dá ẹ̀sìn èké mọ̀, ó sì tún dáhùn ìbéèrè yìí pé, Ǹjẹ́ ìsìn kankan tiẹ̀ wà téèyàn lè fọkàn tán?”

Jí! July–August

“À ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kan tó ń jà rànyìn lásìkò tá a wà yìí. Ìyẹn ni ìwà ọdaràn. Àwọn kan sọ pé tí ìjọba bá da ọlọ́pàá tó pọ̀ dáadáa sígboro, ìwà ọ̀daràn á dín kù. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa fòpin sí ìwà ọ̀daràn. [Ka Sáàmù 37:10, 11.] Ìwé yìí sọ̀rọ̀ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe yẹn, ó sì tún sọ àwọn ohun tá a lè ṣe ká má bàa kó sọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn.”

Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!

“À ń sọ̀rọ̀ ìtùnú látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn ní àdúgbò yín. Ìdí nìyẹn tẹ́ ẹ fi rí wa lọ́dọ̀ yín. Ọ̀pọ̀ àwọn tá a ti bá pàdé ló ń ṣe kàyéfì pé báwo ni Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa ṣe lè jẹ́ kí ìyà máa jẹ àwọn èèyàn.” Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé Ìròyìn Ayọ̀ sí Ẹ̀kọ́ 5, ka ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ àti ìkejì kí ẹ sì jọ jíròrò rẹ̀, títí kan àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a fi lẹ́tà wínníwínní kọ. Fún un ní ìwé náà, kí o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìbéèrè tó kàn lára èyí tá a fi lẹ́tà tó dúdú yàtọ̀ kọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́