Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Ìròyìn Ìjọba No. 38
“À ń pín ìwé kan níbi gbogbo láyé, ohun tó sì wà nínú ìwé náà ṣe pàtàkì gan-an. Ìwé tìẹ rèé.”
Àkíyèsí: Kí ẹ lè kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe ṣókí. Àmọ́, nígbà míì ẹni tá à ń wàásù fún lè nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa lóòótọ́, kó sì fẹ́ ká máa bá ọ̀rọ̀ wa lọ. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè béèrè èrò rẹ̀ nípa ìbéèrè tó wà ní iwájú ìwé náà, kí o ka ìdáhùn Bíbélì tó wà nínú rẹ̀ fún un, kí ẹ sì jọ jíròrò díẹ̀ lára ohun tó wà nínú ìwé náà bí àkókò bá ṣe wà sí. Kó o tó fi ibẹ̀ sílẹ̀, fi ìbéèrè tó wà lẹ́yìn ìwé náà lábẹ́ “Ohun Tó Yẹ Kó O Ronú Lé” hàn án kí o sì ṣètò láti pa dà wá kí ẹ lè jọ jíròrò rẹ̀.
Ilé Ìṣọ́ January 1
“À ń lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn ká lè bá wọn sọ̀rọ̀ ní ṣókí nípa ohun kan tó kan gbogbo wa, ìyẹn ikú àwọn èèyàn wa. Ṣé o gbà pé ikú ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan tàbí ìbátan ẹni wà lára ohun tó nira jù lọ láti fara dà láyé yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ ti rí i pé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí máa ń tu àwọn nínú. [Ka Aísáyà 25:8.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò ìlérí tó ń fúnni níṣìírí tí Bíbélì ṣe pé Ọlọ́run máa mú ikú kúrò, ó sì máa jí àwọn èèyàn wa tó ti kú dìde.”
Ji! January–February
“À ń lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn torí a kíyè sí i pé ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn ò balẹ̀ mọ́, ìdí sì ni pé ìwà rere kò wọ́pọ̀ mọ́ láwùjọ. Ǹjẹ́ ìwọ náà rò pé àwọn èèyàn ò ka ìwà rere sí pàtàkì mọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìwà àwọn èèyàn máa yí pa dà. [Ka 2 Tímótì 3:1-5.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí tá a fi lè gbà pé àwọn ìwà rere tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ṣeé tẹ̀ lé lóòótọ́.”