Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní December: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú èyíkéyìí tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. January: A máa pín ìwé Ìròyìn Ìjọba No. 38 lákànṣe, àkòrí rẹ̀ ni, Ǹjẹ́ Àwọn Tó Ti Kú Lè Jíǹde? Tí ẹ bá ti pín gbogbo ìwé Ìròyìn Ìjọba tẹ́ ẹ ní lọ́wọ́ tán kí oṣù tó parí, àwọn akéde lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn ìwé tá a kọ sí ìsàlẹ̀ yìí fún oṣù tó ń bọ̀. February: Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!, Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, Tẹ́tí sí Ọlọ́run, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? tàbí ìwé olójú ewé 32 èyíkéyìí tó bá wà lọ́wọ́. Ẹ lè fún àwọn Mùsùlùmí ní: Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀ tàbí Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run Ló Máa Ṣamọ̀nà Ẹ̀dá Wọ Párádísè. March: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!
◼ Ọjọ́ Friday, April 3 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2015.