Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 6
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 6, 2014
Orin 132 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl ojú ìwé 3 àti orí 1, ìpínrọ̀ 1 sí 9 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 1-5 (10 min.)
No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 4:1-16 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì Tí Ó Ya Ọlọ̀tẹ̀—td 10D (5 min.)
No. 3: Ohun Tó Mú Kí Jésù Jẹ́ Olùkọ́ Ńlá—lr orí 1 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù January. Ìjíròrò. Fi ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan tọ́ka sí àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ January 1, 2014, kó o sì ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn. Lẹ́yìn náà, kí wọ́n tún sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! January-February, 2014. Bí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka 1 Kọ́ríńtì 9:19-23. Ẹ jíròrò bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
Orin 7 àti Àdúrà