Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè “Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Nínú Ìgbàgbọ́”
Inú wa dùn gan-an láti rí bí Jèhófà ṣe ń bù kún iṣẹ́ kíkó àwọn èèyàn jọ tá à ń ṣe, tó fi jẹ́ pé ó lé ní ẹgbàá márùnlélọ́gọ́fà [250,000] èèyàn tó ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún. (Diu. 28:2) Tí akéde kan bá ran ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ débi tó fi ṣèrìbọmi, akéde náà lè máa wò ó pé kóun dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró kó lè gbájú mọ́ bá ṣe ran àwọn míì lọ́wọ́. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé akẹ́kọ̀ọ́ náà ló máa fẹ́ dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró kó lè lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Àmọ́, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìpìlẹ̀ tó dáa kí wọ́n lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú òtítọ́. Ó yẹ kí wọ́n “ta gbòǹgbò” nínú Kristi kí wọ́n bàa lè “fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.” (Kól. 2:6, 7; 2 Tím. 3:12) Nítorí náà, lẹ́yìn tí akẹ́kọ̀ọ́ kan bá ṣe ìrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ títí tó fi máa parí ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni àti ìwé “Ìfẹ́ Ọlọ́run.”—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti April 2011, ojú ìwé 2.