ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/13 ojú ìwé 7
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
km 12/13 ojú ìwé 7

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní December 30, 2013. A fi déètì tá a máa jíròrò kókó ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan sínú àwọn ìbéèrè náà kẹ́ ẹ lè ṣèwádìí wọn nígbà tẹ́ ẹ bá ń múra sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

1. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìwà tútù hàn sí àwọn aláṣẹ? (Títù 3:2) [Nov. 4, w03 4/1 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 18 sí 19]

2. Kí la lè rí kọ́ látinú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fún Fílémónì bó ṣe wà nínú ìwé Fílémónì 4, 5 àti 7? [Nov. 4, w08 10/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1 sí 2; w92 4/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 2]

3. Báwo la ṣe lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run? (Héb. 4:9-11) [Nov. 11, w11 7/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 16 sí 17]

4. Kí la kọ́ lára Sámúẹ́lì, àwọn onídàájọ́ àtàwọn wòlíì olóòótọ́ tí wọ́n ṣiṣẹ́ “òdodo” yọrí? (Héb. 11:32, 33) [Nov. 18, w11 1/1 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 5 sí 6]

5. Kí nìdí tí Jákọ́bù fi sọ pé “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè a kọ́kọ́ mọ́ níwà, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà”? (Ják. 3:17) [Nov. 25, w11 8/15 ojú ìwé 30 sí 31 ìpínrọ̀ 15]

6. Àwọn wo ni “òkú” tí a “polongo ìhìn rere fún”? (1 Pét. 4:6) [Dec. 2, w08 11/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 8]

7. Nínú 1 Jòhánù 2:7, 8, àṣẹ wo ni Jòhánù sọ pé ó jẹ́ “láéláé,” tó sì tún jẹ́ “tuntun”? [Dec. 9, w08 12/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 6]

8. Ta ni àwọn orúkọ oyè yìí, “Ááfà àti Ómégà,” àti “Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn” ń tọ́ka sí? (Ìṣí. 1:8, 17) [Dec. 16, w09 1/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 6]

9. Ọ̀nà méjì wo ni Ọlọ́run gbà “fi èdìdì di” àwọn ẹni àmì òróró? (Ìṣí. 7:3) [Dec. 23, w07 1/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 2]

10. Kí nìdí tó fi dá wa lójú hán-únhán-ún pé àwọn ìbùkún tí Ọlọ́run ṣèlérí máa ní ìmúṣẹ lábẹ́ Ìjọba rẹ̀, kí ló sì yẹ kí èyí mú ká ṣe? (Ìṣí. 21:5, 6) [Dec. 30, re ojú ìwé 304 ìpínrọ̀ 9]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́