Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 30
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 30
Orin 126 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jl Ẹ̀kọ́ 26 sí 28 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìṣípayá 15-22 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: “Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè ‘Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Nínú Ìgbàgbọ́.’” Àsọyé. Lẹ́yìn náà, ṣe àṣefihàn ṣókí nípa bá a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù January. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n jáde òde ẹ̀rí lọ́jọ́ yẹn.
10 min: Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kó Lè Di Akéde. Àsọyé tá a gbé ka ojú ìwé 82, ìpínrọ̀ 1 sí 2, nínú ìwé A Ṣètò Wa. Fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu òbí kan tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere tó ní ọmọ tó jẹ́ akéde tí kò tíì ṣe ìrìbọmi. Báwo ló ṣe ran ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ kó lè tẹ̀ síwájú tó fi tóótun láti di akéde?
10 min: A Kò Dá Nìkan Wà. (2 Ọba 6:16) Ìjíròrò tá a gbé ka Ìwé Ọdọọdún ti 2013, ojú ìwé 47, ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 48, ìpínrọ̀ 2. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
Orin 119 àti Àdúrà